Àwọn Ẹyọ-owó Tí Ó Ní Orúkọ Ọlọrun
WO ÀWỌN ẹyọ-owó fàdákà tí a fi hàn níhìn-ín fínnífínní. Olùṣàkóso Germany Wilhelm V ni ó rọ wọ́n nígbà ìjọba rẹ̀ láti 1627 sí 1637. Nígbà náà lọ́hùn-ún, àárín-gbùngbùn ilẹ̀ Europe ń lọ́wọ́ nínú Ogun Ọlọ́gbọ̀n Ọdún, ìjàkadì láàárín àwọn Katoliki àti Protẹstanti. Wilhelm V gbèjà àjọ Protẹstanti. Láti lè pèsè iye owó tí ó ga lọ́lá tí ìforígbárí yìí ń béèrè, ó kó gbogbo fàdákà rẹ̀ ó sì fi wọ́n rọ àwọn ẹyọ-owó.
Ní ọ̀nà tí ó dùnmọ́ni, àwòrán tí ó wà lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ẹyọ-owó náà fi òòrùn tí ó yí orúkọ Ọlọrun, Jehofa, ká hàn ní ọ̀nà àmì Tetragrammaton ti èdè Heberu. Ọ̀pẹ tún wà níbẹ̀, tí ó dúró fún okun. Ohun tí ó túmọ̀ sí ni pé igi náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀fúùfù ti jẹ́ kí ó tẹ̀, dúró láìṣẹ́ lábẹ́ ààbò Ọlọrun. Àkọlé èdè Latin tí ó wà lára ẹyọ-owó náà ní orúkọ Jehofa ó sì fi ìgbọ́kànlé hàn nínú ìtọ́jú aláàbò rẹ̀.
Dípò títọrọ ààbò Jehofa, irú lílo orúkọ Ọlọrun lọ́nà báyìí jẹ́ asán nítòótọ́, nítorí pé Jehofa kì í gbèjà ẹnìkankan nínú ìforígbárí oníwà-ipá ti aráyé. Ní tòótọ́, Ogun Ọlọ́gbọ̀n Ọdún náà kò lè ní ìfọwọ́sí Ọlọrun. Ìwé gbédègbéyọ̀ Funk & Wagnalls New Encyclopedia sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìfojúdíwọ̀n tí a fìṣọ́ra ṣe, èyí tí ó ju ìdajì lọ nínú àwọn ará Germany ni ó parun nígbà ogun náà. Àìlóǹkà àwọn ìlú-ńlá, àwọn ìlú, àwọn abúlé, àti àwọn oko àwọn ará Germany ni ó parun pátápátá. Ohun tí ó súnmọ́ ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn ohun-èlò ilé-iṣẹ́ ńlá, ohun ọ̀gbìn, àti ìṣòwò ti Germany ni ó parun.”
Lílo orúkọ náà Jehofa lára àwọn ẹyọ-owó wọ̀nyí ránni létí àṣẹ tí a fún Israeli pé: “Ìwọ kò gbọdọ̀ lo orúkọ Jehofa Ọlọrun rẹ lọ́nà tí kò níláárí.” (Eksodu 20:7, NW) Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ẹyọ-owó wọ̀nyí jẹ́rìí síi pé orúkọ àtọ̀runwá náà, Jehofa, ni àwọn ènìyàn Germany ti mọ̀ dáradára tipẹ́tipẹ́. Báwo ni o ti mọ Ọlọrun tí ń jẹ́ orúkọ yìí dáradára tó?