Àwọn Obìnrin Káàkiri Ayé
NÍGBÀ tí tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọrun, Jehofa sàsọtẹ́lẹ̀ àbájáde oníjàábá tí yóò dé sórí àwọn méjèèjì àti àwọn àtọmọdọ́mọ wọn. Jehofa wí fún Efa pé: “Lọ́dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí, òun ni yóò sì máa ṣe olórí rẹ.” (Genesisi 3:16) Ìgbà gbogbo ni Bibeli fún ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún àwọn obìnrin ní ìṣírí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn obìnrin sì máa ń gbádùn ìgbésí-ayé tí ó túbọ̀ kún fún ayọ̀, tí ó tẹ́nilọ́rùn síi nítorí pé àwọn àti àwọn ìdílé wọn ń fi àwọn ìlànà Bibeli sílò.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ti sọ, bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin mìíràn káàkiri ayé ni a ń tẹ́lógo, tí a ń rẹ́jẹ, tí a sì ń rẹ̀nípòwálẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde International Herald Tribune, nígbà tí ó sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn náà, sọ pé: “Pẹ̀lú kúlẹ̀kúlẹ̀ tí a fìṣọ́ra ṣe, ìròyìn lórí 193 orílẹ̀-èdè . . . fi ipò tí ó bani nínú jẹ́ hàn nípa àìbánilò lọ́gbọọgba àti ìwà rírorò sí àwọn obìnrin.”
Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀: Ní àárín gbùngbùn Africa, àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin gbọ́dọ̀ ṣe èyí tí ó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ oko tí ń tánnilókun, ìdá mẹ́ta nínú wọn ni ó sì máa ń lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ bíi ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin. Ní orílẹ̀-èdè kan níbẹ̀, panṣágà kò bófinmu fún àwọn obìnrin ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ọkùnrin. Òfin orílẹ̀-èdè Africa mìíràn kan yọ̀ọ̀da fún ọkọ kan láti pa aya rẹ̀ bí ó bá ká a mọ ibi tí ó ti ń ṣe panṣágà, ṣùgbọ́n òfin náà kò yọ̀ọ̀da fún aya náà láti pa ọkọ rẹ̀ bí ó bá bá a ní irú ipò kan náà.
Ìròyìn náà sọ pé ní àwọn apá ibi kan ní South America, àwọn ọlọ́pàá kì í fi ojú àánú hàn sí àwọn obìnrin tí a lù bátabàta. Àwọn obìnrin òṣìṣẹ́ pẹ̀lú sì níláti faramọ́ owó oṣù tí ó fi ìpín 30 sí 40 nínu ọgọ́rùn-ún dín sí ti àwọn ọkùnrin.
Ní àwọn apá ibi kan ní Asia, àwọn obìnrin ń jìyà dídi ẹni tí a sọ di aláìlèbímọ àti ìṣẹ́yún. Ní orílẹ̀-èdè kan, àwọn aṣẹ́wó tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 500,000 ni ó wà, ọ̀pọ̀ àwọn tí ó jẹ́ pé àwọn òbí tí ń wá owó láti ra ilé titun fún ara wọn ni ó tà wọ́n sínú òwò aṣẹ́wó. Àwọn ọlọ́pàá ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn gbọ́dọ̀ kojú “ikú owó ìdána” tí ń gbalẹ̀gbòde—ìyàwó kan ni ọkọ tàbí ìdílé ọkọ lè pa nítorí pé owó ìdána rẹ̀ kò bá iye tí wọ́n ń retí mu.
Nípa Jesu Kristi, Bibeli fún wa ní ìdánilójú pé: “Yóò gba aláìní nígbà tí ó bá ń ké: tálákà pẹ̀lú, àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun óò dá tálákà àti aláìní sí, yóò sì gba ọkàn àwọn aláìní là. Òun óò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ìwà-agbára: iyebíye sì ni ẹ̀jẹ̀ wọn ní ojú rẹ̀.” (Orin Dafidi 72:12-14) Nítorí náà ìdí wà fún wa láti máa fojúsọ́nà fún rere; àwọn obìnrin káàkiri ayé lè máa fojúsọ́nà fún ipò tí a mú sunwọ̀n síi tí yóò wà ní àkókò yẹn.