Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
“Wọ́n Ń Bá A Lọ Láìdábọ̀”
LÁTI ọjọ́ Jesu Kristi àti àwọn aposteli rẹ̀, àwọn aṣáájú ìsìn ti lọ jìnnà nínú ìsapá wọn láti ké ìwàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun nígbèrí. Léraléra ni àwọn aláṣẹ ìbílẹ̀ ní Jerusalemu “pa àṣẹ ìdarí” ní pàtó fún àwọn aposteli láti ‘máṣe máa kọ́ni lórí ìpìlẹ̀ orúkọ Jesu.’ (Ìṣe 5:27, 28, 40) Síbẹ̀síbẹ̀, àkọsílẹ̀ Bibeli sọ pé “ọ̀rọ̀ Ọlọrun ń bá a lọ ní gbígbilẹ̀, iye awọn ọmọ-ẹ̀yìn sì túbọ̀ ń pọ̀ síi ní Jerusalemu.”—Ìṣe 6:7.
Ẹgbàá ọdún lẹ́yìn náà a ṣì rí àwọn aṣáájú-ìsìn ní Israeli tí ń lo agbára ìdarí lórí àwọn aláṣẹ ìbílẹ̀ láti dí iṣẹ́ àwọn Kristian tòótọ́ lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè náà. Lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ tí àwọn aláṣerégèé onísìn gbé kani lórí, ní November 1987, àwọn aláṣẹ ìbílẹ̀ ní Tel Aviv, Israeli, pàṣẹ fún àwọn Ẹlẹ́rìí láti dáwọ́ ṣíṣe ìpàdé Kristian dúró ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower. Àṣẹ náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní October 1989. Ní ṣíṣe ìgbọràn sí èyí, àwọn Ẹlẹ́rìí náà pàdé ní àwọn ilé lílò tí a háyà ní agbègbè náà fún ọdún mẹ́ta nígbà tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ di èyí tí a kò lò rárá.
Láàárín àkókò yìí, a mú ọ̀ràn náà wá sí àfiyèsí Ilé-Ẹjọ́ Gíga ti Israeli. Ọ́fíìsì adájọ́ àgbà orílẹ̀-èdè náà ṣàyẹ̀wò ìjiyàn tí àwọn Ẹlẹ́rìí gbé kalẹ̀ ó sì polongo pe ìgbèjà fún ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wọn kò lè ṣeé ṣe lójú-ìwòye ẹ̀tanú ìsìn rírékọjá ààlà tí ó wémọ́ ọn. Nípa bẹ́ẹ̀, kò sí ohun tí àwọn aláṣẹ ìbílẹ̀ lè ṣe ju kí wọ́n yí ìpinnu wọn padà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sì fi tayọ̀tayọ̀ padà sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn.
Iṣẹ́ wíwàásù òtítọ́ Bibeli ha fàsẹ́yìn láàárín àwọn ọdún wọ̀nyẹn bí? Rárá o! Ní àkókò tí a ti Gbọ̀ngàn Ìjọba náà pa, ìjọ méjì ni ó wà ní Tel Aviv àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kékeré kan sì wà ní ìlú Lod tí ó wà nítòsí. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, nígbà tí a ṣí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà padà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti pọ̀ síi di ìjọ mẹ́rin, àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli titun kan sì ń pàdé ní Beersheba.
Ìdàgbàsókè ní Israeli kò mọ sórí àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ èdè pàtàkì, Arabic àti Heberu. Àwọn olùṣílọ-sí-ilẹ̀-mìíràn ti rọ́ wọlé gììrì láti Soviet Union tẹ́lẹ̀rí, nítorí náà ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ń sọ èdè Russian dí nísinsìnyí nínú ṣíṣàjọpín ìhìnrere náà pẹ̀lú wọn. Àwọn ìpàdé lédè Russian ni a ti ń ṣe ní ìjọ mẹ́ta; iye tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ènìyàn pàdé pọ̀ fún àpèjọ lèdè Russian láìpẹ́ yìí.
Láìsí iyèméjì, àwọn ẹlẹ́tanú ìsìn yóò máa bá ìgbétáásì wọn lòdì sí ìjọsìn tòótọ́ nìṣó. Ṣùgbọ́n àwọn olùpòkìkí Ìjọba ń bá a nìṣó láti máa ṣàfarawé àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ínní tí ó jẹ́ pé, “wọ́n . . . ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni ati pípolongo ìhìnrere nipa Kristi naa, Jesu,” láìka àtakò sí.—Ìṣe 5:42.