Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Kí A Bẹ̀ Ọ́ Wò Bí?
Àní nínú ayé onídààmú yìí, ìwọ lè jèrè ayọ̀ láti inú ìmọ̀ pípéye ti Bibeli nípa Ọlọrun, Ìjọba rẹ̀, àti ète àgbàyanu rẹ̀ fún aráyé. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú síi tàbí bí ìwọ yóò bá fẹ́ kí ẹnì kan kàn sí ọ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ pẹ̀lú rẹ, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú tí a tò sí ojú-ìwé 2.