A Tún Ìfàjẹ̀sínilára Dàrò
NÍNÚ sànmánì yìí tí ó dágùdẹ̀ fún àrùn AIDS, ìhalẹ̀mọ́ni tí ó tí ì ga jùlọ fún ìlera aláìsàn kan ní ilé-ìwòsàn lè jẹ́ yàrá iṣẹ́-abẹ. Dókítà Richard Spence, ẹni tí ó ti darí Ibùdó Ìṣègùn Iṣẹ́-Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀ ní Cooper Hospital-University Medical Center ní Camden, New Jersey, U.S.A., fún ohun tí ó lé ní ẹ̀wádún sọ pé: “Kò sí ọ̀nà kankan tí a fi lè mú kí ìpèsè ẹ̀jẹ̀ bọ́ pátápátá lọ́wọ́ àrùn.”
Kò yanilẹ́nu pé, ibùdó náà ń ṣètọ́jú ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, àwọn ẹni tí a ti mọ̀ dáradára fún kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti gba ìfàjẹ̀sínilára gẹ́gẹ́ bí a ti gbé e karí Bibeli. (Lefitiku 17:11; Ìṣe 15:28, 29) Bí ó ti wù kí ó rí, bákan náà ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ni wọ́n ń farahàn ní ibùdó náà, nítorí àníyàn wọn nípa àwọn ewu tí ó ṣeé ṣe kí ó bá ìfàjẹ̀sínilára rìn, èyí tí ó ní nínú kíkó àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀, àrùn AIDS, àti àwọn àrùn mìíràn. Ìwé ìròyìn Courier-Post Weekly Report on Science and Medicine ṣàkíyèsí pé: “Àrùn AIDS tí ń jẹyọ ti fi àìní tí ó wà fún yíyẹ ẹ̀jẹ̀ wò hàn. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀ràn kan ṣì tún lè yọ́ kọjá nínú àyẹ̀wò náà nítorí pé ẹnì kan lè ní kòkòrò náà ṣáájú kí ó tó farahàn nínú àyẹ̀wò.”
Nítorí irú àwọn ewu báyìí, Ibùdó Ìṣègùn Iṣẹ́-Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀ ń lo àwọn àfidípò fún ìfàjẹ̀sínilára, èyí tí ó ní nínú títún ẹ̀jẹ̀ aláìsàn náà fúnra rẹ̀ fà sí i lára padà—ọgbọ́n ìgbàṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí kan lè ṣe aláìkọ̀ lábẹ́ àwọn ipò kan.a Ìtọ́jú mìíràn ní nínú lílo àwọn òògùn kan tí ń mú kí ìpèsè ẹ̀jẹ̀ aláìsàn náà yá kánkán. Ní àfikún síi, àgbélẹ̀rọ àfidípò ẹ̀jẹ̀ ni a máa ń lò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti mú kí mímú afẹ́fẹ́ wá láìnílò ìfàjẹ̀sínilára gbé pẹ́ẹ́lí síi. Dókítà Spence sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fẹ́ àbójútó ìlera tí ó dára jùlọ, ṣùgbọ́n wọ́n fẹ́ àfidípò fún ìfàjẹ̀sínilára.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dúpẹ́ fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti àtìlẹ́yìn tí wọ́n ti rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn dókítà tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún ìdálójú-ìgbàgbọ́ wọn níti ìsìn. Ní ìyọrísí rẹ̀, wọ́n ti gba “ìtọ́jú ìṣègùn tí ó dára jùlọ” nítòótọ́ wọ́n sì ti di ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ́ gaara mú níwájú Jehofa Ọlọrun.—2 Timoteu 1:3.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìjíròrò lórí ọ̀nà ìgbàṣe yìí àti àwọn kókó-abájọ tí ó ní nínú ní ṣíṣe ìpinnu ara-ẹni, tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀rí-ọkàn ni a là lẹ́sẹẹsẹ nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti March 1, 1989, ojú-ìwé 30 sí 31.