Ìtura Àlàáfíà fún Àwọn Òjìyà Aláìmọwọ́mẹsẹ̀
ÒUN ni ìwà-ọ̀daràn tí ó kóni nírìíra jùlọ tí ènìyàn tíì ṣe rí—fífi ọmọ ṣe ààtò ìrúbọ. Àwọn kan kò gbàgbọ́ pé irú àṣà bíburú lékenkà bẹ́ẹ̀ ti lè ṣẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n àmì ìdánimọ̀ àwọn ará Foniṣia olùjọsìn wọ̀nyí ni ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwárí àwọn awalẹ̀pìtàn ti jẹ́rìí sí.
Àwọn ọmọ tí wọ́n wá láti ìdílé tí ó gbayì ni a fi rúbọ nínú iná sí irú ọlọrun bíi Tanit àti Baali-Hammoni. Ní Carthage àwọn ọ̀dọ́ òjìyà ni a sun gẹ́gẹ́ bí ohun ìrúbọ sí ère bàbà ti Kronos. Diodorus Siculus, òpìtàn ti ọ̀rúndún kìn-ínní B.C.E., sọ pé àwọn mọ̀lẹ́bí ọmọ náà ni a kò yọ̀ọ̀da fún láti sọkún. Bóyá wọ́n gbàgbọ́ pé ẹkún làásìgbò wọn lè dín ìníyelórí ìrúbọ náà kù.
Fún àkókò kan irú ààtò kan náà ni a ṣe nítòsí Jerusalemu ní Tofeti ìgbàanì. Àwọn olùjọsìn níbẹ̀ yóò máa jó wọn yóò sì máa lu ìlù láti lè bo igbe ọmọ náà mọ́lẹ̀ bí wọ́n ṣe jù ú sí ikùn Moleki tí iná ti ń jó.—Jeremiah 7:31.
Jehofa bínú gidigidi sí àwọn wọnnì tí wọ́n fi pẹ̀lú àìláàánú di etí wọn sí ìrora àwọn ẹlòmíràn. (Fiwé Owe 21:13.) Bí Ọlọrun ti ń fi ìyọ́nú hàn fún àwọn ọmọdé, dájúdájú Jehofa yóò fi irú àwọn òjìyà aláìlọwọ́mẹsẹ̀ bẹ́ẹ̀ kún “àjíǹde awọn olódodo ati awọn aláìṣòdodo.”—Ìṣe 24:15; Eksodu 22:22-24.