ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 9/15 ojú ìwé 31
  • Ààtò Àṣà Aláìnítumọ̀ Kẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ààtò Àṣà Aláìnítumọ̀ Kẹ̀?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 9/15 ojú ìwé 31

Ààtò Àṣà Aláìnítumọ̀ Kẹ̀?

SÁKÁRÁMẸ́ǸTÌ ìjẹ́wọ́ ni àwọn Katoliki ti ń ṣe fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Síbẹ̀, lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó jẹ́ ìgbòkègbodò déédéé kan tí kò wúlò. Ní ríronú padà sẹ́yìn sí ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀, ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bob sọ pé: “Mo jẹ́ ọ̀dọ́langba, àní bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, n kò kà á sí ohun pàtàkì kan.” Èé ṣe? Lójú tirẹ̀, ìjẹ́wọ́ ti di ààtò àṣà kan tí kò ní ìtumọ̀. Ó ṣàlàyé pé: “Ìjẹ́wọ́ dà bíi kíkó gbogbo ẹrù rẹ tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ wá sọ́dọ̀ ọkùnrin aṣọ́bodè kan ní pápá ọkọ̀ òfuurufú. Ó béèrè àwọn ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, lẹ́yìn náà, ó sì yọ̀ọ̀da kí o máa lọ lẹ́yìn tí o ti san ohun kan fún àwọn nǹkan ṣíṣeyebíye tí o rà, nígbà tí o wà ní òkè òkun.”

Ní ọ̀nà kan náà, Frank Wessling, nígbà tí ó ń kọ̀wé nínú ìwé ìròyìn U.S. Catholic, ṣàpèjúwe àṣà ìjẹ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí “ìtọ́sọ́nà tí a mú rọrùn jùlọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, la ìgbà àwọn àdúrà ìrònúpìwàdà ìjẹ́wọ́ tí a há sórí kọjá, sí ìṣe ìjẹ́wọ́ ráńpẹ́ náà.” Kí ni ìparí èrò Wessling? Ó sọ pé: “Ó dá mi lójú kedere pé Ìjẹ́wọ́ dára fún ọkàn. Ṣùgbọ́n ọ̀nà tí àwọn Katoliki gbà ń ṣe é jẹ́ ìṣòro.”

Bibeli fi ìjẹ́wọ́ hàn ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀ gédégbé. Èyí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni jíjẹ́wọ́ fún Ọlọrun. (Orin Dafidi 32:1-5) Kristian ọmọ ẹ̀yìn náà, Jakọbu, kọ̀wé pé: “Ẹnikẹ́ni ha wà tí ń ṣàìsàn láàárín yín bí? Kí ó pe awọn àgbà ọkùnrin ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì gbàdúrà lé e lórí, ní fífi òróró pa á ní orúkọ Jehofa. Nitori naa ẹ máa jẹ́wọ́ awọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ní gbangba wálíà fún ara yín lẹ́nìkínní kejì kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín lẹ́nìkínní kejì, kí ẹ lè gba ìmúláradá.”—Jakọbu 5:14‚ 16.

Kristian kan tí ẹ̀ṣẹ̀ di ẹrù ìnira lé lórí lè pe àwọn alábòójútó ìjọ, tí wọ́n lè fún un ní ìmọ̀ràn ti ara ẹni tí ó gbéṣẹ́ láti inú Bibeli láti ran oníwà àìtọ́ náà lọ́wọ́ láti pa ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tì. Àwọn alábòójútó lè fún un ní ìṣírí tí ó yẹ bí wọ́n ti ń wo ìtẹ̀síwájú ẹni náà tí ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí. Ẹ wo bí èyí ti yàtọ̀ sí ààtò àṣà ìjẹ́wọ́ tí a ń ṣe nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì lónìí tó! Bí a ti fún un lókun pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ara ẹni láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà ìjọ, oníwà àìtọ́ tí ó ronú pìwà dà náà lè jèrè ìtura àlàáfíà tí Dafidi ní ìmọ̀lára rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ ọ́ nínú psalmu kan pé: “Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ, àti ẹ̀ṣẹ̀ mi ni èmi kò sì fi pamọ́. Èmi wí pé, èmi óò jẹ́wọ́ ìrékọjá mi fún Oluwa: ìwọ sì dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.”—Orin Dafidi 32:5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́