ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 11/1 ojú ìwé 2-4
  • Àwọn Áńgẹ́lì Ha Wà Láàárín Wa Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Áńgẹ́lì Ha Wà Láàárín Wa Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìfẹ́ fún Áńgẹ́lì Ti Gba Àwọn Èèyàn Lọ́kàn
    Jí!—1999
  • Wíwádìí Ìròyìn náà Wò
    Jí!—1999
  • Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìwọ Ha Ní Áńgẹ́lì Kan Tí Ń dáàbò Bò Ọ́ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 11/1 ojú ìwé 2-4

Àwọn Áńgẹ́lì Ha Wà Láàárín Wa Bí?

Ó ṣẹlẹ̀ ní mọ̀nàwàá. Níbi tí ó ti ronú lọ, tí kò sì mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ láyìíká rẹ̀, Marilynn dọ́gbẹ̀ẹ́rẹ́ lọ sí ipa ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin. Lójijì, ó gbọ́ ìró fakafìkì. Ó gbójú sókè, ó sì rí i pé ọ̀gangan ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin kan tí ń bọ̀ ni òun dúró sí! Marilynn gan sóòró, ojora gbagbára lọ́wọ́ọ rẹ̀. Ọkọ̀ ojú irin náà sún mọ́ ọn débi tí ó fi lè rí ojú adarí ọkọ̀ náà tí jìnnìjìnnì ti bò. Láé, Marilynn kò jẹ́ gbàgbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e. Ó ní: “Àfi bíi pé òmìrán kan taari mi látẹ̀yìn. Mo fò kúrò lójú ipa ọ̀nà náà, mo sì ṣubú sórí àjókù èédú ilẹ̀ ní gẹ̀rẹ́ ipa ọ̀nà náà.” Marilynn fara pa níwọ̀nba, ó dìde láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tí ó yọ ọ́ nínú ewu—àmọ́ kò rí ẹnì kankan níbẹ̀! Kí ni ìparí èrò rẹ̀? Marilynn sọ pé: “Áńgẹ́lì olùṣọ́ mi gba ẹ̀mí mi là. Ta ló ha tún lè jẹ́?”

ÓDÀ bíi pé ayé ẹlẹ́mìí iyèméjì gbé ọ̀rọ̀ àwọn áńgẹ́lì lérí ẹ̀mí lójijì. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ẹ̀dá ọ̀run ti di kókó inú àwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n, sinimá, àti eré kan ní ilé ìwòran Broadway pàápàá. Àwọn ìwé nípa àwọn áńgẹ́lì wà lára àwọn ìwé ìsìn tí ń tà jù lọ. Àwọn ẹgbẹ́, ìpàdé àpérò, àti ìwé ìròyìn alábala ń bẹ ti ń jẹ́ orúkọ áńgẹ́lì. A ti dá àwọn àpèjọ àpérò sílẹ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́—bí ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ kan ti sọ ọ́—láti “mú kí ‘áńgẹ́lì inú’ rẹ tì ọ́ lẹ́yìn.’”

Àwọn oníṣòwò ajìfà ń fìrọ̀rùn lo àǹfààní èrò wíwọ́pọ̀ nípa áńgẹ́lì láti ta àìníye àwọn ọjà àràlò. Alájọni ilé ìtajà kan ní United States sọ pé: “Àdùrà ni ohunkóhun tí ó bá ti ní àwòrán áńgẹ́lì lára.” Ní àfikún sí ọ̀pọ̀ ìwé nípa áńgẹ́lì, ó dárúkọ “àwọn ère, ohun ọ̀ṣọ́ àlẹ̀máṣọ, ọmọláńgidi, ẹ̀wù alápá kúkúrú, bébà àlẹ̀mógiri àti káàdì ìkíni tí ó ní àwòrán áńgẹ́lì lára”—gbogbo wọn para pọ̀ di ohun tí akọ̀ròyìn kan pè ní “èrè ọ̀run.”

Àwọn alágbàwí ọ̀ràn áńgẹ́lì tẹnu mọ́ ọn pé èyí kì í ṣe àṣà ìgbàlódé lásán. Láti ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn, wọ́n pèsè ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹ̀rí—àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ “ojú ayé” nípa ìfojúkojú pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì. Àwọn kan sọ pé, àwọn rí áńgẹ́lì kan ní ìrísí ènìyàn. Àwọn mìíràn rí ìmọ́lẹ̀ kan, wọ́n gbọ́ ohùn kan, wọ́n nímọ̀lára wíwà níbẹ̀, tàbí ìrọni, tí wọ́n gbà gbọ́ pé ó jẹ́ ti áńgẹ́lì. Bíi ti Marilynn, ọ̀pọ̀ sọ pé áńgẹ́lì kan gba ẹ̀mí àwọn là.

Kí ní ń ṣẹlẹ̀? Joan Wester Anderson, tí ó ti kọ ìwé méjì nípa ìfojúkojú pẹ̀lú “àwọn ajẹ̀dálọ,” wí pé: “Mo rò pé jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí tún ń ru sókè bọ̀.” Alma Daniel, tí ó ṣèrànwọ́ láti kọ ìwé mìíràn, gbé ìgbésẹ̀ kan síwájú sí i. Ó sọ pé, “a ti pàṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì láti sọ ara wọn di mímọ̀ nísinsìnyí, kí a lè túbọ̀ dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ìdí tí a fi ń rí ohun púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nípa wọn ni pé, wọ́n fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀. Wọ́n ń ṣe é.”

Èyí ha rí bẹ́ẹ̀ ní ti gidi bí? Tàbí ohun mìíràn ha ń bẹ lẹ́yìn fífà tí àwọn áńgẹ́lì ń fani mọ́ra ní lọ́ọ́lọ́ọ́ bí? Láti mọ̀, a gbọ́dọ̀ yẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wò. Bí a óò ṣe rí i, Bibeli ní òtítọ́ nípa àwọn áńgẹ́lì nínú.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Ojú ìwé 3 àti 4: The New Testament: A Pictorial Archive from Nineteenth-Century Sources, láti ọwọ́ Don Rice/Dover Publications, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́