Oúnjẹ Inú Àpótí Ń Jẹ́rìí
NÍ ÀWỌN ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé ìmìtìtì ilẹ̀ ní Kobe, Japan, ní January tó kọjá, ó ṣòro fún àwọn ènìyàn ní agbègbè tí ọ̀ràn kàn náà láti rí oúnjẹ. Síbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò ṣaláìní, ọpẹ́ ni fún ìrànlọ́wọ́ onínúure àwọn ará wọn. Àwọn ìjọ ìtòsí pèsè àkàṣù ìrẹsì fún ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìmìtìtì náà. Láìpẹ́, àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n bìkítà ń pèsè àwọn oúnjẹ inú àpótí. Ọ̀pọ̀ lára wọn lẹ àwọn ìwé pélébé mọ́ wọn, tí ń sọ nípa ìdàníyàn fún àwọn tí ọ̀ràn kàn. Àwọn tí ó gba oúnjẹ náà wí pé, “omijé dà” sí oúnjẹ kọ̀ọ̀kan, bí wọn kò ti lè pa á mọ́ra nígbà tí wọ́n ń ka àwọn ìwé pélébé náà.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣàjọpín oúnjẹ wọn pẹ̀lú àwọn mìíràn tí kò ní. Ẹlẹ́rìí kan ń jẹun nígbà tí ó ń rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ pẹ̀lú alábàáṣiṣẹ́pọ̀ kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ kan náà. Nítorí náà, ó ṣàjọpín ọ̀kan lára àwọn oúnjẹ inú àpótí tí ó ti gbà pẹ̀lú rẹ̀.
Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ náà béèrè pé: “Ibo lo ti ra oúnjẹ inú àpótí yìí?” Arákùnrin náà ṣàlàyé iṣẹ́ ìpèsè ìrànwọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe. Pẹ̀lú ìmọrírì, ọkùnrin náà sọ pé: “N kò tí ì fẹnu kan ẹ̀fọ́ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. N óò tọ́jú díẹ̀ lọ sílé fún ìdílé mi.”
Nígbà kẹta tí ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ náà kó 3,000 owó yen (nǹkan bí $35, U.S.) fún Ẹlẹ́rìí náà, ó sì sọ pé: “Mo ti di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbòkègbodò yín, nítorí náà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n ṣe ìtọrẹ fún iṣẹ́ yín. Mo mọrírì ṣíṣàjọpín oúnjẹ rẹ pẹ̀lú mi. Ní tòótọ́, gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ jẹ́ irú ènìyàn àtàtà bẹ́ẹ̀.”