ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 11/15 ojú ìwé 20
  • Àwọn Abo-Ọlọrun Ogun àti Afúnnilọ́mọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Abo-Ọlọrun Ogun àti Afúnnilọ́mọ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 11/15 ojú ìwé 20

Àwọn Abo-Ọlọrun Ogun àti Afúnnilọ́mọ

NÍGBÀ ìgbétásì ìwalẹ̀pìtàn kan ní Ebla, Siria, a rí ohun ìṣẹ̀m̀báyé kan tí a fi gbẹ́ ère Ishtar, abo-ọlọrun ogun àti afúnnilọ́mọ ti àwọn ará Babiloni. Awalẹ̀pìtàn Paolo Matthiae júwe rẹ̀ bí “ìdérí rubutu tí ó ní àmì ẹgbẹ́ awo tí ó dúró fún àlùfáà obìnrin tí ó dagọ̀ bojú níwájú ère ọlọrun àrà ọ̀tọ̀ kan . . . tí a so orí rẹ̀ mọ́ òpó gíga tẹ́ẹ́rẹ́ kan.”

Àwárí náà ṣe pàtàkì, nítorí pé ère náà ti wà láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejìdínlógún Ṣáájúu Sànmánì Tiwa. Gẹ́gẹ́ bí Matthiae ti sọ, èyí pèsè “ẹ̀rí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀” pé ìjọsìn Ishtar bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí 2,000 ọdún sẹ́yìn.

Ìjọsìn Ishtar bẹ̀rẹ̀ ní Babiloni, ó sì tàn jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Romu ní àwọn ọ̀rúndún tí ó tẹ̀ lé e. Jehofa pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israeli láti mú gbogbo ohun tí ó bá jẹ mọ́ ìsìn èké kúrò ní Ilẹ̀ Ìlérí náà, ṣùgbọ́n, nítorí pé wọ́n kùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀, ìjọsìn Aṣtoreti (tí ó jẹ́ alábàádọ́gba Ishtar nílẹ̀ Kenaani) di ìdẹkùn fún wọn.—Deuteronomi 7:2, 5; Onidajọ 10:6.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ishtar àti alábàádọ́gba rẹ̀ Aṣtoreti kò sí mọ́, àwọn ìwà tí wọ́n ṣojú fún—ìwà pálapàla àti ìwà ipá—gbalé gbòde. Ó dára láti béèrè bóyá àwùjọ òde òní yàtọ̀ dáadáa ní ti gidi sí ti àwọn ọ̀làjú ìgbàanì tí ń jọ́sìn àwọn abo-ọlọrun ogun àti afúnnilọ́mọ wọ̀nyí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

A fi àwọn ọmọdé pẹ̀lú rúbọ sí Tanit

[Credit Line]

Ralph Crane/Bardo Museum

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́