Àlàáfíà Ha Ṣeé Ṣe bí?
“GBOGBO ìgbà ni ogun yóò máa wà níbì kan. Òtítọ́ tí ó bani nínú jẹ́ nípa aráyé nìyẹn.” Ojú ìwòye nǹkan kò lè dára yìí fara hàn nínú lẹ́tà kan láti ọwọ́ òǹkàwé ìwé ìròyìn Newsweek láìpẹ́ yìí. Ìwọ́ ha fara mọ́ ọn bí? Ogun kò ha ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, tí àlàáfíà kò sì ṣeé ṣe bí? Bí a bá fi ojú ohun tí ìtàn wí wò ó, ó di dandan kí ìdáhùn wa jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sí àwọn ìbéèrè méjèèjì yìí. Láti ìgbà tí a ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àkọsílẹ̀, aráyé ti ń kó wọnú ogun kan tẹ̀ lé òmíràn, ìforígbárí sì ń yọrí sí ìparun síwájú àti síwájú sí i, bí ènìyàn ti ń rí àwọn ọ̀nà tí ó túbọ̀ gbéṣẹ́ láti pa ara wọn.
Ti ọ̀rúndún ogún kò yàtọ̀. Ní tòótọ́, òun ni ó tí ì rí ogun tí ó gba ẹ̀mí ènìyàn jù lọ, ṣùgbọ́n ó tún ti rí ohun tuntun mìíràn. Ní 50 ọdún sẹ́yìn, United States ṣe ìfilọ́lẹ̀ sànmánì átọ́míìkì nípa jíju bọ́m̀bù átọ́míìkì méjì sí Japan. Ní ẹ̀wádún márùn-ún láti ìgbà náà wá, àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣe ìtòjọpelemọ àwọn nǹkan ìjà átọ́míìkì tí ó lè pa aráyé run ní àpatúnpa. Pé àwọn ohun ìjà átọ́míìkì wà, yóò ha dáyà fo ènìyàn láti má ṣe jagun nígbẹ̀yìn gbẹ́yín bí? Òtítọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ dáhùn ìbéèrè yìí. Láti 1945 wá, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti kú nínú ogun—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, títí di ìsinsìnyí, a kò tí ì ju bọ́m̀bù átọ́míìkì míràn.
Èé ṣe tí ìran aráyé ṣe jẹ́ arógunyọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia Americana mẹ́nu kan àwọn apá kan nínú ìbágbépọ̀ aráyé tí ìtàn ti fi hàn pé ó ti yọrí sí ogun. Nínú wọn ni ṣíṣàìfàyè gba ìsìn àwọn ẹlòmíràn, ẹ̀yà ìran tèmi lọ̀gá, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ yíyàtọ̀ síra, ìjẹ́wọ́ èrò yíyàtọ̀ (bíi ètò ìjọba Kọ́múníìsì àti èto ìṣòwò bòḿbàtà), ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni àti ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ òmìnira orílẹ̀-èdè, ipò ọrọ̀ ajé àti ẹ̀mí ìfogunyanjú ọ̀ràn tí ó gbajúmọ̀. Nígbà tí o ka àkọsílẹ̀ yìí, o ha rí ohunkóhun tí ó ṣeé ṣe kí ó yí padà ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́ bí? Ọwọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yóò ha rọlẹ̀ ní pípinnu láti máa tọ́jú òmìnira wọn bí? Àwọn ènìyàn yóò ha jáwọ́ nínú kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà bí? Ìgbawèrèmẹ́sìn ti àwọn onígbàgbọ́ ẹ̀kọ́ oréfèé yóò ha dín kù bí? Kò dájú pé yóò rí bẹ́ẹ̀.
Nígbà náà, kò ha sí ìrètí kankan, pé ní ọjọ́ kan, nǹkan yóò dára sí i, tí àlàáfíà pípẹ́ títí yóò sì wà bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ìrètí wà. Láìka rúkèrúdò ayé yìí sí, ó ṣeé ṣe lónìí pàápàá láti rí àlàáfíà. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti ṣe bẹ́ẹ̀. Jẹ́ kí a sọ nípa díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí fún ọ, kí o sì rí ẹ̀kọ́ tí ó lè rí kọ́ nínú ìrírí wọn.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Àwòrán ẹ̀yìn ìwé àti ti ojú ewé 32: Reuters/Bettmann
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Reuters/Bettmann