ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 1/15 ojú ìwé 30
  • Ìtẹ̀síwájú Òjijì Nínú Ọ̀ràn Òfin

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtẹ̀síwájú Òjijì Nínú Ọ̀ràn Òfin
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 1/15 ojú ìwé 30

Ìtẹ̀síwájú Òjijì Nínú Ọ̀ràn Òfin

NÍ April 1995, a ja àjàṣẹ́gun ẹjọ́ mánigbàgbé kan. Ó bẹ̀rẹ̀ ní January 28, 1992, nígbà tí a dá Luz Nereida Acevedo Quiles, ẹni ọdún 24, dúró sí Ilé Ìwòsàn El Buen Pastor ní Puerto Rico fún iṣẹ́ abẹ bí-o-bá-fẹ́. Gbàrà tí a dá a dúró, ó fẹnu sọ ọ́, ó sì kọ ọ́ sílẹ̀ pé gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, òun kì yóò gba ẹ̀jẹ̀ sára. (Ìṣe 15:28, 29) Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn tí ọ̀ràn kàn, títí kan dókítà tí ó tọ́jú rẹ̀, mọ ìfẹ́ inú rẹ̀ dáradára.

Ọjọ́ méjì lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà, Luz pàdánù ẹ̀jẹ̀ púpọ̀, àìtó ẹ̀jẹ̀ kọ lù ú, nítorí ẹ̀jẹ̀ tí kò dá bọ̀rọ̀. Dókítà tí ń tọ́jú rẹ̀, Dókítà José Rodríguez Rodríguez, gbà gbọ́ pé, ọ̀nà kan ṣoṣo tí a fi lè ràn án lọ́wọ́ ni láti fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára. Nítorí náà, láìfi tó o létí tàbí kí ó fohùn ṣọ̀kan, ó béèrè fún àṣẹ ilé ẹjọ́ láti fa ẹ̀jẹ̀ sí Luz lára.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Luz ṣì nímọ̀lára dáradára, tí ó sì lè sọ̀rọ̀ fúnra rẹ̀, Dókítà Rodríguez Rodríguez ranrí pé, nítorí bí ọ̀ràn náà ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó, kò sì àkókò láti béèrè ìfohùnṣọ̀kan ẹnikẹ́ni. Agbẹjọ́rò àgbègbè náà, Eduardo Pérez Soto, fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà, adájọ́ àgbègbè náà, Ọlọ́lá Ángel Luis Rodríguez Ramos, fún un ní àṣẹ ilé ẹjọ́ fún ìfàjẹ̀sínilára náà.

Nípa bẹ́ẹ̀, ní January 31, 1992, wọ́n gbé Luz lọ sí iyàrá iṣẹ́ abẹ, níbi tí wọ́n ti fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára. Nígbà tí ìfàjẹ̀sínilára náà ń lọ lọ́wọ́, ó gbọ́ tí àwọn kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn ń rẹ́rìn-ín. Àwọn mìíràn fi ọ̀rọ̀ gún un lára, ní sísọ pé, ohun tí wọ́n ń ṣe jẹ́ fún àǹfààní ara rẹ̀. Ó jà dé ibi ti agbára rẹ̀ mọ—ṣùgbọ́n pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí. Ní òpin ọjọ́ náà, wọ́n ti fa ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ mẹ́rin sí Luz lára.

Ọ̀ràn Luz kì í ṣe àkọ́kọ́ tàbí ìkẹyìn nínú èyí tí ó kan ìfàjẹ̀sínilára àti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Puerto Rico. Kí èyí tó ṣẹlẹ̀, ó kéré tán, a ti fúnni ní àṣẹ ilé ẹjọ́ 15 fún ìfàjẹ̀sínilára ní ìlòdì sí ìfẹ́ inú àwọn tí wọ́n dàgbà, tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa, a sì ti fúnni ní púpọ̀ sí i láti ìgbà náà. Ó bani nínú jẹ́ pé, nínú ẹjọ́ kan, wọ́n ṣiṣẹ́ lé àṣẹ ilé ẹjọ́ náà, a sì fipá fa ẹ̀jẹ̀ sí agbàtọ́jú kan lára nígbà tí kò nímọ̀lára mọ́.

Ṣùgbọ́n, ìjà Luz kò pin sí iyàrá iṣẹ́ abẹ. Ní October 1993, a pé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Puerto Rico lẹ́jọ́. Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù ni ó gbọ́ ẹjọ́ náà, nígbà tí ó sì di April 18, 1995, a dá Luz láre. Ilé ẹjọ́ náà sọ pé, àṣẹ náà láti fa ẹ̀jẹ̀ síni lára “kò bá òfin mu, ó sì fi ẹ̀tọ́ ṣíṣe ìsìn tí ó wuni, ẹ̀tọ́ lórí ọ̀ràn ara ẹni àti ìpinnu lórí ara ẹni láìsí fífi ẹsẹ̀ òfin tọ̀ ọ́, du olùfisùn náà.”

Ìdájọ́ yìí jẹ́ mánigbàgbé, nítorí pé, èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí ilé ẹjọ́ ní Puerto Rico yóò dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láre nínú ẹjọ́ kan tí ó kan ìfàjẹ̀sínilára. Ìdájọ́ náà ru ìhùwàpadà yíyani lẹ́nu sókè. A ṣe ìpàdé àpérò kan, tí àwọn oníròyìn ìwé ìròyìn pàtàkì, ilé iṣẹ́ rédíò, àti tẹlifíṣọ̀n pésẹ̀ sí.

Ní òru ọjọ́ kan náà yẹn, èto orí rédíò kan gbé ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò Luz sáfẹ́fẹ́. Wọ́n ké sí àwọn àwùjọ olùgbọ́ láti tẹ̀ wọ́n láago, kí wọ́n sì béèrè ìbéèrè. Ọ̀pọ̀ dókítà àti agbẹjọ́rò tẹ̀ wọ́n láago, wọ́n sì fi ìhùwàpadà tí ó fara mọ́ ẹjọ́ náà hàn. Ẹnì kan tí ó tẹ̀ wọ́n láago sọ pé: “Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kò tí ì sọ pẹ̀lú ìdálójú pé, ìfàjẹ̀sínilára lè gba ẹ̀mí là, ẹ̀tàn sì ni ó jẹ́ láti ronú lọ́nà yẹn.” Ó tún sọ pé: “Láìpẹ́, ìfàjẹ̀sínilára yóò wà nínú ìtàn gẹ́gẹ́ bí ìmẹ́hẹ àti àṣìṣe ńlá tí ìmọ̀ ìṣègùn òde òní ti ṣe.”

Lẹ́yìn náà, ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ òfin kan, tí a buyì fún gidigidi, tẹ ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society láago, ó sì sọ ìtẹ́lọ́rùn jíjinlẹ̀ rẹ̀ jáde pẹ̀lú ohun tí ó pè ní “àjàyè amóríwú.” Ó fi kún un pé, kì í ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti ẹ̀tọ́ òfin nìkan ni ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà gbé lékè, bí kò ṣe gbogbo àwọn ọmọ Puerto Rico.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́