Jọ́sìn Jehofa Pẹ̀lú Ọwọ́ Mímọ́ Tónítóní
LÁBẸ́ ìmísí, Dafidi onipsalmu náà sọ pé: “Èmi óò wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀: bẹ́ẹ̀ ni èmi óò sì yí pẹpẹ rẹ ká, Oluwa.”—Orin Dafidi 26:6.
Nígbà tí ó ń kó àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jọ, ó lè jẹ́ pé àṣà ìbílẹ̀ àwọn àlùfáà ọmọ Lefi Israeli, láti gun àtẹ̀gùn pẹpẹ náà kí wọ́n sì gbé ẹbọ wọn lé orí iná ni Dafidi ń tọ́ka sí. Ṣùgbọ́n ṣáájú kí wọ́n tó ṣe ààtò ìjọsìn yìí, a béèrè pé kí àwọn àlùfáà fọ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn. Èyí kì í ṣe ohun kékeré. Bí àlùfáà kan bá kọ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ yìí, ó lè yọrí sí ikú rẹ̀!—Eksodu 30:18-21.
Fífọ nǹkan lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ń yọrí sí ìmọ́tónítóní nípa tẹ̀mí àti ti ìwà híhù. (Isaiah 1:16; Efesu 5:26) Jehofa ń fẹ́ kí a máa ‘yí pẹpẹ rẹ̀ ká’ lónìí nípa ṣíṣiṣẹ́ sìn-ín. Ṣùgbọ́n ó ń béèrè pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ mímọ́ tónítóní—gẹ́gẹ́ bí Dafidi ṣe sọ ọ́, ọwọ́ tí a fọ̀ mọ́ ‘láìlẹ́ṣẹ̀.’ Èyí kì í ṣe ohun àbéèrèfún kékeré rárá, nítorí pé àwọn tí ń hùwà àìmọ́ kì yóò jogún Ìjọba Ọlọrun. (Galatia 5:19-21) Ìgbé ayé nínú iṣẹ́ oníwà-bí-Ọlọ́run kò fún ẹnì kan ní àǹfààní láti máa lọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla. Nípa báyìí, aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Emi ń lu ara mi kíkankíkan mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú, pé, lẹ́yìn ti mo bá ti wàásù fún awọn ẹlòmíràn, kí emi fúnra mi má baà di ẹni tí a kò fi ojúrere tẹ́wọ́gbà lọ́nà kan ṣáá.”—1 Korinti 9:27.
Àwọn tí wọ́n ń wá ìtẹ́wọ́gbà àtọ̀runwá àti ayọ̀ tòótọ́ gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ sin Jehofa pẹ̀lú ọwọ́ mímọ́ tónítóní. Bí i Dafidi, wọ́n ń rìn “ní òtítọ́ ọkàn, àti ní ìdúró ṣinṣin.”—1 Awọn Ọba 9:4.