ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 2/1 ojú ìwé 15
  • ‘Wọ́n Ń Tàn Bí Atànmọ́lẹ̀ Nínú Ayé’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Wọ́n Ń Tàn Bí Atànmọ́lẹ̀ Nínú Ayé’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fifi Ẹ̀jẹ̀ Gba Ẹmi Là—Bawo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Rí I Pé O Wo Fídíò No Blood—Medicine Meets the Challenge
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Ẹ Rin Gẹgẹ Bi Jehofa Ti fun Yin ni Itọni
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Mo Fara Mọ́ Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 2/1 ojú ìwé 15

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

‘Wọ́n Ń Tàn Bí Atànmọ́lẹ̀ Nínú Ayé’

ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA yàtọ̀ pátápátá, wọ́n sì sábà máa ń pariwo wọn lọ́nà búburú nítorí pé, wọn kì í gbẹ̀jẹ̀ sára. Ṣùgbọ́n, a gbé ipò yìí karí Bibeli lọ́nà tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in. Ó fi hàn pé, Ọlọrun dẹ́bi fún àṣìlò ẹ̀jẹ̀, níwọ̀n bí ẹ̀jẹ̀ ti jẹ́ ohun ṣíṣeyebíye lójú rẹ̀. (Genesisi 9:3, 4; Lefitiku 17:14) Nítorí yíyẹ Ìwé Mímọ́ wò lórí kókó yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa parí èrò pé, lọ́nà tí ó ṣe kedere, àṣẹ Bibeli láti ‘takété sí ẹ̀jẹ̀’ yóò ní àṣà ìfàjẹ̀sínilára ti òde òní nínú.—Ìṣe 15:19, 20, 28, 29.

Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn mẹ́ḿbà àwùjọ oníṣègùn àti àwọn ilé ẹjọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ti kín àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lẹ́yìn lórí ọ̀ràn yìí. Fún àpẹẹrẹ, ní Denmark, ìjàm̀bá ọkọ̀ ṣokùnfà ikú abiyamọ kan tí ó mọ ojú ìwòye Bibeli nípa ẹ̀jẹ̀ dáradára. Nítorí pé ó kọ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀ sára, àwọn dókítà rẹ̀ súnná sí ìgbétásì ìkóguntini nípasẹ̀ àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn fún odindi oṣù kan, ní ìlòdìsí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.

Àwọn òbí obìnrin náà béèrè fún ìwádìí, nígbà tí ó sì di April 1994, Àjọ Tí Ń Bójú Tó Ẹ̀sùn Àwọn Olùgbàtọ́jú ní Denmark kéde ìpinnu kan. Ó sọ pé, kì í ṣe kíkọ ẹ̀jẹ̀ ni ó pa olùgbàtọ́jú náà, bí kò ṣe àìmọṣẹ́níṣẹ́ àwọn oníṣègùn. A gbé ìpinnu náà karí ìwádìí tí Àjọ Afìmọ̀ Ìṣègùn Ṣẹjọ́ àti àwọn aláṣẹ ètò ìlera ṣe. Nínú àtẹ̀jáde kán sí gbogbo ilé ìwòsàn ní Denmark, Àjọ Tí Ń Bójú Tó Ìlera Jákèjádò Orílẹ̀-Èdè náà sọ pé, ní gbígbé kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀ yẹ̀ wò, ojúṣe àwọn dókítà ni láti fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ìtọ́jú àfidípò dídára jù lọ tí ó bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó.

Ẹjọ́ mìíràn kan Dan, Ẹlẹ́rìí tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 15, tí àrùn àìtó ẹ̀jẹ̀ pa. Nínú ẹjọ́ yìí, àwọn dókítà bọ̀wọ̀ fún ìpinnu onígboyà tí Dan ṣe láti kọ ìfàjẹ̀sínilára. Èyí yọrí sí ìgbétásì gbígbalé gbòde tí àwọn oníròyìn ṣe, nínú èyí tí ilé iṣẹ́ ìròyìn ti dá àwọn dókítà lẹ́bi fún ikú Dan. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò gbà pẹ̀lú ìgbékèéyíde òdì náà.

Fún àpẹẹrẹ, ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ tí Dan ń lọ wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba fún àsọyé ìsìnkú náà. Ẹnu yà á nítorí àwọn ìròyìn tí kò tọ́ tí a kọ́ nípa ikú Dan. Lẹ́yìn tí ó ti béèrè onírúurú ìbéèrè nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, ó gba ẹ̀dà kan fídíò náà, Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name. Fídíò náà wú u lórí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi ṣètò fún gbogbo àwọn olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ náà láti wò ó. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wo fídíò náà, kíláàsì kan lẹ́ẹ̀kan.

Alábòójútó fún ètò ìlera ní Denmark pẹ̀lú kò fara mọ́ bí a ṣe sọ̀rọ̀ àwọn dókítà Dan lọ́nà burúkú. Ó sọ pé, àwọn dókítà ṣe ohun tí ó tọ́, nípa bíbọ̀wọ̀ fún ìpinnu yíyè kooro tí Dan ṣe, àti ìgbàgbọ́ rẹ̀ tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀.

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùpòkìkí Ìjọba wà tí ń ṣègbọràn sí òfin Ọlọrun. Nítorí ìgbọràn wọn, wọ́n yàtọ̀, ‘wọ́n ń tàn bí atànmọ́lẹ̀ nínú ayé.’—Filippi 2:12, 15.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́