Ìwé Orin Tí Irina Yàn Láàyò
LÁÌPẸ́ yìí, Irina, ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́sàn-án láti Sofia, Bulgaria, ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ó fẹ́ràn orin kíkọ́, ní pàtàkì, ó máa ń gbádùn kíkọ àwọn orin inú ìwé Kọrin Ìyìn sí Jehofah. Nítorí náà, Irina fi ṣe góńgó rẹ̀ láti kọ́ àwọn orin díẹ̀ sórí lóṣooṣù.
Ọ̀kan nínú àwọn kókó ẹ̀kọ́ tí Irina yàn láàyò ní ilé ẹ̀kọ́ ni orin. Nítorí náà, ó ya olùkọ́ tí ń kọ́ ọ lórin lẹ́nu, nígbà tí Irina kọ̀ láti kọ orin pẹ̀lú ẹgbẹ́ akọrin ilé ẹ̀kọ́. Èé ṣe tí Irina fi kọ̀? Ó mọ̀ pé, púpọ̀ nínú àwọn orin tí a óò ní kí òún kọ ń fi ogo fún àwọn akọni àti họlidé orílẹ̀-èdè, tí ó pilẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn kèfèrí. Àwọn orin kan tilẹ̀ ń ti ọ̀tẹ̀ àti ìwà ipá lẹ́yìn, láti gbe góńgó orílẹ̀-èdè lárugẹ. Olùkọ́ náà kò lóye ìdúró Irina lórí ọ̀ràn yìí. Irina dorí èrò láti kọ lẹ́tà tí yóò gbé ìdálójú ìgbàgbọ́ ìsìn rẹ̀ kalẹ̀ sí olùkọ́ rẹ̀—ṣùgbọ́n pàbó ni ó já sí.
Bàbá Irina ronú nípa ohun kan. Ó fún olùkọ́ náà ní ẹ̀dà kan ìwé náà, Kọrin Ìyìn sí Jehofah, tí ó ní àwọn orin tí Irina fẹ́ràn láti máa kọ nínú. Ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, olùkọ́ náà ké sí Irina sí iyàrá ìkọrin. Ó ní kí Irina kọ díẹ̀ nínú àwọn orin tí ó yàn láàyò, láti inú ìwé náà—níwájú àwọn ọmọ kíláàsì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀—nígbà tí olùkọ́ náà sì ń bá a tẹ dùùrù sí i. Ó lé ní wákàtí kan tí wọ́n fi kọ orin náà! Olùkọ́ náà gbà pé, ìwé orin tí Irina yàn láàyò ní àwọn orin adùnyùngbà tí ó gbámúṣé nínú.