ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 3/1 ojú ìwé 32
  • Ẹ Jẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Kí Ó Tàn!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Jẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Kí Ó Tàn!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 3/1 ojú ìwé 32

Ẹ Jẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Kí Ó Tàn!

NÍGBẸ̀YÌNGBẸ́YÍN, àkókò tó fún ọkùnrin arúgbó náà láti fojú rí Messia tí a ṣèlérí náà! Nípasẹ̀ ìṣípayá àtọ̀runwá, Simeoni mọ̀ pé “oun kì yoo rí ikú kí ó tó rí Kristi ti Jehofa.” (Luku 2:26) Ṣùgbọ́n ẹ wo bí ó ti runi lọ́kàn sókè tó, nígbà tí Simeoni wọ tẹ́ḿpìlì, tí Maria àti Josefu sì gbé ìkókó náà, Jesu, lé e lọ́wọ́! Ó fìyìn fún Ọlọrun, ní sísọ pé: “Nísinsìnyí, Oluwa Ọba-Aláṣẹ, iwọ ń jẹ́ kí ẹrú rẹ lọ lómìnira ní àlàáfíà . . . nitori ojú mi ti rí ohun àmúlò rẹ fún gbígbanilà . . . ìmọ́lẹ̀ kan fún mímú ìbòjú kúrò lójú awọn orílẹ̀-èdè ati ògo awọn ènìyàn rẹ Israeli.”—Luku 2:27-32; fi wé Isaiah 42:1-6.

Láti ìgbà batisí rẹ̀ ní ẹni 30 ọdún, títí di ìgbà ikú rẹ̀, Jesu fẹ̀rí jíjẹ́ “ìmọ́lẹ̀” ayé hàn. Ní àwọn ọ̀nà wo? Ó tan ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ nípa tẹ̀mí nípa wíwàásù nípa Ìjọba Ọlọrun àti àwọn ète Rẹ̀. Ó tún túdìí àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké, ó sì fi àwọn iṣẹ́ ti ó jẹ́ ti òkùnkùn hàn ní kedere. (Matteu 15:3-9; Galatia 5:19-21) Nítorí náà, Jesu lè fi ẹ̀tọ́ sọ pé: “Emi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”—Johannu 8:12.

Jesu kú ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Ìmọ́lẹ̀ náà ha kú nígbà náà bí? Rárá o! Nígbà tí ó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé, Jesu sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú awọn ènìyàn.” (Matteu 5:16) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, lẹ́yìn ikú Jesu, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mú kí ìmọ́lẹ̀ náà máa tàn lọ.

Ní àfarawé Jesu, àwọn Kristian lónìí ń fi ìmọ́lẹ̀ Jehofa hàn nípa lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Wọ́n ń “bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí awọn ọmọ ìmọ́lẹ̀,” ní fífi ẹ̀rí hàn pé àwọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ tí ń tàn nínú gbígbé ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bíi Kristian.—Efesu 5:8.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́