Ìṣẹ̀lẹ̀ kan Tí Kò Yẹ Kí O Tàsé
“Gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ọrẹ pípé” ń wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, Bàbá wa ọ̀run. (Jakọbu 1:17) Ẹ̀bùn títóbi jù lọ tí Ọlọrun fún aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ìpèsè fún ìràpadà wọn nípasẹ̀ Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, Jesu Kristi. Ikú Jesu gẹ́gẹ́ bí Olùràpadà wa mú kí ìyè àìnípẹ̀kun nínú paradise kan lórí ilẹ̀ aye ṣeé ṣe. Ní Luku 22:19, a pàṣẹ fún wa láti máa ṣe ìrántí ikú rẹ̀.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń fi tìfẹ́tìfẹ́ pè ọ́ láti wá ṣàjọpín kíkọbi ara sí àṣẹ Jesu pẹ̀lú wọn. Ayẹyẹ ọdọọdún yìí yóò wáyé lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní ọjọ́ tí ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú Nisani 14 lórí kàlẹ́ńdà òṣùpá ti Bibeli, èyí tí yóò jẹ́ Tuesday, April 2, 1996. Kọ ọjọ́ yìí sílẹ̀ kí o má baà gbàgbé rẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àdúgbò rẹ yóò sọ ọ̀gangan ibi ìpàdé àti àkókò náà gan-an fún ọ.