ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 6/15 ojú ìwé 32
  • Ó Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Ṣiṣẹ́ Sin Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Ṣiṣẹ́ Sin Jèhófà
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 6/15 ojú ìwé 32

Ó Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Ṣiṣẹ́ Sin Jèhófà

“IBI TÍ o ti ń ṣiṣẹ́ sìn kò ní púpọ̀ ṣe bí kò ṣe ẹni tí ìwọ́ ń ṣiṣẹ́ sìn ni ó ṣe pàtàkì gan-an.” John Booth fẹ́ràn láti máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, ó sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú wọn. Ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, tí ó dópin ní Monday, January 8, 1996, kò gbé iyè méjì kankan dìde nípa ẹni tí òún yàn láti ṣiṣẹ́ sìn.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́kùnrin kan nígbà náà lọ́hùn-ún ní 1921, John Booth ń wá ète ìgbésí ayé kiri. Ó kọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́ ọjọ́ Sunday ní Ṣọ́ọ̀ṣì Alátùn-únṣe ti Dutch, ṣùgbọ́n ó ta ko èro gbígba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti di òjíṣẹ́ nítorí ó ronú pé àwùjọ àlùfáà ń gbé ìgbésí ayé onímọtara ẹni nìkan. Nígbà tí ó rí ìwé ìkéde pélébé kan nípa ọ̀rọ̀ àsọyé tí a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tí Ó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kì Yóò Kú Láé,” lójú ẹsẹ̀, ó ránṣẹ́ fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìwé pélébé náà kéde. Bí ohun tí ó kà ti gbà á lọ́kàn, láìpẹ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í gun kẹ̀kẹ́ ológeere gba kìlómítà 24 lọ sí ìpàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà náà. Ó ṣe batisí ní 1923, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wàásù láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Wallkill, New York, níbi tí ìdílé rẹ̀ ní oko wàrà sí.

Arákùnrin Booth wọnú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ní April 1928. Ó wàásù ní agbègbè ìpínlẹ̀ ìlú rẹ̀, àti ní ìgbèríko Gúúsù, ní fífi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹ àti ibùgbé. Ó ní láti fi ìgboyà kojú àwọn ewu bíi ti àwọn afìbọnhalẹ̀mọ́ni tí wọ́n ni ibi tí a ti ń pọntí líle láìbófinmu, tí ọ̀kan nínú wọn yìnbọn fún aṣáájú ọ̀nà alábàáṣiṣẹ́pọ̀ John Booth, tí ó sì ṣe é léṣe. Ní 1935, a yan Arákùnrin Booth láti jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ àwọn ìjọ àti àwọn àwùjọ kéékèèké káàkiri orílẹ̀-èdè náà wò. Ó ṣètò àwọn àpéjọ, ó sì ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin lọ́wọ́ láti dúró gangan láìka àtakò sí. Kíkojú àwọn ènìyànkénìyàn tí inú ń bí, fífara hàn nílé ẹjọ́, àti jíjìyà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n lápapọ̀ kò jẹ́ tuntun fún Arákùnrin Booth mọ́. Ó kọ̀wé nígbà kan pé: “Bí n óò bá sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn àkókò tí ń ru ìmọ̀lára sókè yẹn, ìwé yóò kún.”

Ní 1941, Joseph F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, pínṣẹ́ yàn fún Arákùnrin Booth láti ṣiṣẹ́ ní Oko Ìjọba, nítòsí Ithaca, New York. Ó fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́ sìn níbẹ̀ fún ọdún 28. Ìfẹ́ rẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ kò jó rẹ̀yìn, jálẹ̀ àwọn ọdún, inú rẹ̀ dùn láti kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower Bible School of Gilead tí ó wà fún dídá àwọn míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́, tí ó wà níbẹ̀ ní Oko Ìjọba títí di 1961. Ní 1970, a sọ fún Arákùnrin Booth láti ṣiṣẹ́ sìn ní Oko Watchtower ní Wallkill, New York, nítorí náà, ó bá ara rẹ̀ ní agbègbè kan náà níbi tí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú ọ̀nà ní nǹkan bí ọdún 45 ṣáájú.

Ní 1974, a yan Arákùnrin Booth sípò gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Brooklyn, New York. Ó fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́ sìn ní ipò yẹn títí di ìgbà ikú rẹ̀ ní ẹni ọdún 93. A fẹ́ràn John Booth fún ìwà ìrẹ̀lẹ̀, àti inú rere àkópọ̀ ìwà Kristẹni rẹ̀ tí ó jinlẹ̀ gidigidi. Títí di ìgbà tí ìlera àti okùn rẹ̀ fi mẹ́hẹ, ó ń fi ìṣòtítọ́ wàásù láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà àti ní àwọn òpópónà ìlú.

Bí àwọn tí ó ṣiṣẹ́ sìn pẹ̀lú rẹ̀ ti ń ṣọ̀fọ̀ ikú rẹ̀, wọ́n rí ìtùnú nínú ìlérí Bíbélì nípa irú àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró bẹ́ẹ̀ pé, a jí wọn dìde sí ìwàláàyè ní ọ̀rún àti pé, “àwọn ohun tí wọ́n ṣe ń bá wọn lọ ní tààràtà.” (Ìṣípayá 14:13; Kọ́ríńtì Kìíní 15:51-54) Ó dájú pé ó jẹ́ agbègbè àyíká tuntun, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọ̀kan tí John Booth yóò ti lè ṣiṣẹ́ sin Jèhófà títí láé!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

John Booth 1903-1996

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

HERALD-AMERICAN, ANDOVER 1234

76 Jehovites Jailed in Joliet

[Credit Line]

Chicago Herald-American

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́