Adájọ́ Tẹ́lẹ̀rí Bẹ̀bẹ̀—Lẹ́yìn Ọdún 45
NÍ YÀRÁ ilé ẹjọ́ kan ní Berlin, ní August 1995, adájọ́ tẹ́lẹ̀rí kan fún Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ sọ ìkábàámọ̀ rẹ̀ jáde fún ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ìwà àìtọ́ kan tí ó ti hù ní nǹkan bí ọdún 45 sẹ́yìn.
Ní October 1950, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Oníjọba-Tiwa-N-Tiwa ti Germany (GDR) dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́sàn-án lẹ́bi rúkèrúdò lòdì sí ìjọba àti ṣíṣe amí. A fi méjì sí ẹ̀wọ̀n gbére, àwọn méje yòókù—títí kan Lothar Hörnig, ẹni ọdún 22, olùjẹ́jọ́ tí ó wà ní ipò kẹ́rin láti apá ọ̀tún nínú àwòrán yìí—ni a fi sí ẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ.
Ogójì ọdún lẹ́yìn náà, orílẹ̀-èdè GDR di ara Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Germany. Láti ìgbà náà wá, àwọn aláṣẹ ti ṣèwádìí nípa àwọn àìṣèdájọ́ òdodo mélòó kan tí a ṣe ní orílẹ̀-èdè GDR àtijọ́, wọ́n sì ti gbìyànjú láti dá sẹ̀ríà fún àwọn tí igbá ọ̀rọ̀ náà ṣí mọ́ lórí. Ọ̀kan nínú irú àìṣèdájọ́ òdodo bẹ́ẹ̀ ní ìgbẹ́jọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe ní 1950.
A. T., ẹni 80 ọdún nísinsìnyí, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn adájọ́ tí wọ́n ṣèdájọ́ nígbà tí a fi gbẹ́jọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́sàn-án náà. Nísinsìnyí tí a fẹ̀sùn yíyí ìdájọ́ po kàn án, ó fara hàn níwájú Ilé Ẹjọ́ Ẹlẹ́kùnjẹkùn ní Berlin láti ṣàlàyé ìdájọ́ rẹ̀.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí ilé ẹjọ́, adájọ́ tẹ́lẹ̀rí náà gbà pé òún ti dìbò fún ìdájọ́ ẹ̀bi ní ọdún 45 sẹ́yìn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òún fara mọ́ ìfinisẹ́wọ̀n ọlọ́jọ́ kúkúrú. Ṣùgbọ́n ìgbẹ́jọ́ náà mú òún tún inú rò. Èé ṣe? Nazi ṣenúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ti Hitler lẹ́yìn. Lẹ́yìn ogun náà, a tún ṣenúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí, lọ́tẹ̀ yìí láti ọwọ́ ìjọba Kọ́múníìsì. Èyí mú kí adájọ́ náà “banú jẹ́ gidigidi.”
Lothar Hörnig sọ fún ilé ẹjọ́ pé, òun lo ọdún márùn-ún àti ààbọ̀ ní àdádó ọgbà ẹ̀wọ̀n, a kò sí dá òun sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Brandenburg títí di 1959. Bí ó ti gbọ́ gbólóhùn Hörnig, adájọ́ tẹ́lẹ̀rí náà bú sẹ́kún. Ó sọ pẹ̀lú omijé pé: “Mo kábàámọ̀ gidigidi. Jọ̀wọ́ dárí jì mí.” Hörnig tẹ́wọ́ gba ẹ̀bẹ̀ náà.—Fi wé Lúùkù 23:34.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Neue Berliner Illustrierte