Ìbẹ̀wò Sí Ilẹ̀ Ìlérí
KÁ NÍ ọ̀rẹ́ kan sọ fún ọ pé òún ti ra ilé tuntun kan tí ó wà ní àyíká rírẹwà, tí ó pa rọ́rọ́—gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn—fún ọ. Ìwọ yóò ṣe kàyéfì pé: ‘Báwo ni ó ṣe rí?’ Dájúdájú ìwọ yóò hára gàgà láti fojú ara rẹ rí ilé yìí, láti rin inú rẹ̀ kiri, kí o sì yẹ yàrá kọ̀ọ̀kan wò. Ó ṣe tán, ilé rẹ tuntun ni èyí!
Ní ọdún 1473 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì ní ilé tuntun kan—Ilẹ̀ Ìlérí, agbègbè ìpínlẹ̀ gígùn tí ó tó nǹkan bíi 500 kìlómítà láti àríwá sí gúúsù, tí ó sì gbòòrò ní nǹkan bíi kìlómítà 55 ní ìpíndọ́gba.a Níwọ̀n bí ó ti wà ní Agbègbè Ilẹ̀ Ọlọ́ràá, Ilẹ̀ Ìlérí jẹ́ ibi tí ó dùn mọ́ni láti gbé, tí àwọn ohun ṣíṣàrà ọ̀tọ̀ sì bu ẹwà kún un.
Ṣùgbọ́n lónìí, èé ṣe tí ó fi yẹ kí o ní ọkàn-ìfẹ́ nínú “ilé” kan tí a fi fún ẹlòmíràn kan, ní pàtàkì, ẹnì kan tí ó gbé ayé ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn? Nítorí pé ìmọ̀ nípa ilẹ̀ tí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìtàn yìí lè mú kí ìmọrírì rẹ fún àkọsílẹ̀ òtítọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ Bíbélì jinlẹ̀ sí i. Olóògbé Ọ̀jọ̀gbọ́n Yohanan Aharoni kọ̀wé pé: “Ní àwọn ilẹ̀ tí a ti kọ Bíbélì, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti ìwàláàyè inú rẹ̀ òun ìtàn wọnú ara wọn pẹ́kípẹ́kí débi pé kò sí èyíkéyìí tí a lè lóye ní ti gidi láìsí ìrànwọ́ ìkejì.” Síwájú sí i, olórí gbogbo rẹ̀ ni pé, Ilẹ̀ Ìlérí pèsè àpẹẹrẹ kékeré nípa ohun tí Párádísè lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run yóò túmọ̀ sí láìpẹ́ fún aráyé kárí ayé!—Aísáyà 11:9.
Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, Jésù Kristi lo àwọn ohun tí a sábà máa ń rí ní Ilẹ̀ Ìlérí láti fi kọ́ni ní àwọn ẹ̀kọ́ gbígbéṣẹ́. (Mátíù 13:24-32; 25:31-46; Lúùkù 13:6-9) Àwa pẹ̀lú lè kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n láti inú àgbéyẹ̀wò àwọn apá fífani mọ́ra pàtó nípa Palẹ́sìnì ìgbàanì. Nítorí náà, kí a sọ̀rọ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ kí a rìn káàkiri àwọn yàrá rẹ̀ mélòó kan, ní ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ohun ṣíṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ilẹ̀ yìí, tí ó jẹ́ ibùgbé fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Gẹ́gẹ́ bí a óò ti rí i, ohun púpọ̀ ni a lè rí kọ́ láti Ilẹ̀ Ìlérí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí a ṣe lo “Ilẹ̀ Ìlérí” nínú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí gbé àwọn nǹkan yẹ̀ wò láti ojú ìwòye ìgbàanì, gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbé e kalẹ̀ nínú Bíbélì, kò sì ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ohun tí àwọn olóṣèlú tàbí onísìn òde òní ń sọ nípa ẹkùn náà.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Ẹ̀yìn ìwé: Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Garo Nalbandian