ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 8/15 ojú ìwé 21
  • Ìwọ́ Ha Rántí Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ́ Ha Rántí Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • ‘Ẹ Máa Bá a Lọ Ní Dídáríji Ara Yín Lẹ́nì Kíní Kejì’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ṣé Ọlọ́run Máa Dárí Jì Mí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • ‘Ilé Àdúrà fún Gbogbo Àwọn Orílẹ̀-èdè’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 8/15 ojú ìwé 21

Ìwọ́ Ha Rántí Bí?

Ìwọ ha ti mọrírì kíka àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ àìpẹ́ yìí bí? Tóò, wò ó bí o bá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:

◻ Àwọn ọ̀rọ Jésù náà pé, “Bí ẹ̀yin bá dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ji ènìyàn èyíkéyìí, wọ́n wà ní èyí tí a dárí jì wọ́n,” ha túmọ̀ sí pé, àwọn Kristẹni lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini bí? (Jòhánù 20:23)

Kò sí ìdí kankan tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu fún píparí èrò sí pé àwọn Kristẹni ní gbogbogbòò, tàbí àwọn alàgbà tí a yàn sípò nínú ìjọ pàápàá, ní ọlá àṣẹ àtọ̀runwá láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini. Ó dà bí ẹni pé àyíká ọ̀rọ̀ Jésù fi hàn pé, àwọn àpọ́sítélì ní agbára àrà ọ̀tọ̀ nípasẹ̀ ìṣiṣẹ́ ẹ̀mí, láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini tàbí láti má ṣe dárí rẹ̀ jini. (Wo Ìṣe 5:1-11; Kọ́ríńtì Kejì 12:12.)—4/15, ojú ìwé 28.

◻ Kí ni ó tayọ lọ́lá nípa ìtumọ̀ J. J. Stewart Perowne lórí Orin Dáfídì, tí a kọ́kọ́ tẹ̀ jáde ní ọdún 1864?

Nínú ìtumọ̀ rẹ̀, Perowne gbìyànjú láti dìrọ̀ “tímọ́tímọ́ mọ́ àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù náà, nínú àkànlò èdè rẹ̀ àti nínú ọ̀nà ìgbà kọ gbólóhùn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan.” Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó fọwọ́ sí mímú orúkọ àtọ̀runwá náà padà bọ̀ sípò nínú àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà “Jèhófà.”—4/15, ojú ìwé 31.

◻ Ìtọ́sọ́nà wo ni Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa ìbálò wọn pẹ̀lú àwọn ìjọba ayé?

Jésù wí pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Mátíù 22:21) Ó tún wí pé: “Bí ẹnì kan tí ó wà lábẹ́ ọlá àṣẹ bá sì fi tipátipá gbéṣẹ́ fún ọ fún ibùsọ̀ kan, bá a dé ibùsọ̀ méjì.” (Mátíù 5:41) Níhìn-ín, Jésù ń ṣàkàwé ìlànà fífi tinútinú fi ara wa sábẹ́ àwọn ohun tí ó tọ́, yálà nínú àjọṣe ẹ̀dá ènìyàn tàbí nínú àwọn ohun tí ìjọba ń béèrè fún, tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin Ọlọ́run. (Lúùkù 6:27-31; Jòhánù 17:14, 15)—5/1, ojú ìwé 12.

◻ Kí ni ó túmọ̀ sí láti “rìn nínú òtítọ́”? (Orin Dáfídì 86:11)

Èyí kan ṣíṣègbọràn sí àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè àti ṣíṣiṣẹ́ sìn ín pẹ̀lú ìṣòtítọ́ àti òótọ́ inú. (Orin Dáfídì 25:4, 5; Jòhánù 4:23, 24)—5/15, ojú ìwé 18.

◻ Kí ni rírán tí Jèhófà rán Jónà lọ sí Nínéfè ṣàṣeparí rẹ̀?

Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ìgbòkègbodò ìwàásù Jónà ní Nínéfè fi ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín àwọn ará Nínéfè olùronúpìwàdà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ọlọ́rùn-líle hàn, àwọn tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rárá. (Fi wé Diutarónómì 9:6, 13; Jónà 3:4-10.)—5/15, ojú ìwé 28.

◻ Ta ni Ejò náà, ta sì ni “obìnrin náà” tí a tọ́ka sí nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15?

Ejò náà kì í ṣe ejò rírẹlẹ̀, ṣùgbọ́n, ó jẹ́ ẹni tí ó lò ó, Sátánì Èṣù. (Ìṣípayá 12:9) “Obìnrin náà” kì í ṣe Éfà, ṣùgbọ́n, ó jẹ́ ètò àjọ Jèhófà ní ọ̀run, ìyá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó fi ẹ̀mí yàn lórí ilẹ̀ ayé. (Gálátíà 4:26)—6/1, ojú ìwé 9.

◻ Báwo ni ẹnì kan ṣe lè jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá, kí ó sì rí ààbò? (Ìṣípayá 18:4)

Ó gbọ́dọ̀ ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pátápátá kúrò nínú àwọn ètò àjọ ìsìn èké àti kúrò nínú àwọn àṣà wọn àti ẹ̀mí tí wọ́n ń gbé jáde, lẹ́yìn náà, kí ó wá ààbò lọ sínú ètò àjọ ìṣàkóso Jèhófà. (Éfésù 5:7-11)—6/1, ojú ìwé 18.

◻ Èé ṣe tí a fi sábà máa ń mẹ́nu kan idì léraléra nínú Ìwé Mímọ́?

Àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì tọ́ka sí ànímọ́ idì láti ṣàkàwé àwọn nǹkan bí ọgbọ́n, ààbò àtọ̀runwá, àti ìyára kánkán.—6/15, ojú ìwé 8.

◻ Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí tí wọ́n ní ìrètí orí ilẹ̀ ayé, ha ní ẹ̀mí Ọlọ́run bákan náà bí àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró ti ní i bí?

Ní ṣàkó, ìdáhùn ni pé bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀mí Ọlọ́run wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní ìwọ̀n kan náà fún ẹgbẹ́ méjèèjì, a sì nawọ́ ìmọ̀ àti òye sí àwọn méjèèjì lọ́gbọọgba.—6/15, ojú ìwé 31.

◻ Èé ṣe tí ó fi ṣàǹfààní fún wa lónìí, láti ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ tí àwọn àlùfáà Ísírẹ́lì ṣe nínú tẹ́ḿpìlì ní Jerúsálẹ́mù?

Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a lè wá túbọ̀ lóye ìṣètò aláàánú náà ní kíkún, nínú èyí tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lónìí ti lè tún padà bá Ọlọ́run rẹ́. (Hébérù 10:1-7)—7/1, ojú ìwé 8.

◻ Báwo ni tẹ́ḿpìlì kejì tí a kọ́ sí Jerúsálẹ́mù ṣe ní ògo tí ó pọ̀ ju èyí tí Sólómọ́nì kọ́ lọ?

Tẹ́ḿpìlì kejì fi ọdún 164 wà pẹ́ ju tẹ́ḿpìlì Sólómọ́nì lọ. Àwọn olùjọsìn púpọ̀ sí i láti ilẹ̀ púpọ̀ sí i rọ́ wá sí àwọn àgbàlá rẹ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, tẹ́ḿpìlì kejì yìí ní ìyàtọ̀ gíga lọ́lá ti pé Ọmọkùnrin Ọlọ́run, Jésù Kristi, kọ́ni nínú àwọn àgbàlá rẹ̀.—7/1, ojú ìwé 12, 13.

◻ Nígbà wo ni Ọlọ́run mú tẹ́ḿpìlì rẹ̀ nípa tẹ̀mí wá?

Èyí jẹ́ ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa, nígbà tí Ọlọ́run fi hàn pé òún gbọ́ àdúrà tí Jésù gbà nígbà ìbatisí rẹ̀. (Mátíù 3:16, 17) Nípa tẹ̀mí, títẹ́wọ́ tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ìgbékalẹ̀ ara Jésù túmọ̀ sí pé pẹpẹ kan, tí ó tóbi lọ́lá ju ti èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ, ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.—7/1, ojú ìwé 14, 15.

◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a máa dárí jini?

Dídárí ji olùṣeláìfí kan tí ó ti tọrọ àforíjì ṣe kókó bí a bá fẹ́ pa ìṣọ̀kan Kristẹni mọ́. Kèéta àti dídi kùnrùngbùn yóò já àlàáfíà ọkàn gbà mọ́ wa lọ́wọ́. Bí a bá jẹ́ aláìlèdáríjini, ewu náà ń bẹ pé lọ́jọ́ kan, Jèhófà yóò dẹ́kun dídárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. (Mátíù 6:14, 15)—7/15, ojú ìwé 18.

◻ Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe lè di mímọ́?

Ìjẹ́mímọ́ ṣeé ṣe kìkì nípa níní ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, Ọlọ́run mímọ́, àti nípa ìjọsìn mímọ́ gaara wọn sí i. Wọ́n nílò ìmọ̀ pípéye nípa “Ẹni Mímọ́ Jù Lọ” kí wọ́n baà lè jọ́sìn rẹ̀ pẹ̀lú ìjẹ́mímọ́, nínú ìmọ́tónítóní ti ara àti ti ẹ̀mí. (Òwe 2:1-6; 9:10)—8/1, ojú ìwé 11.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́