ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 9/1 ojú ìwé 32
  • “Má Ṣe Lé Wọn Síta!”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Má Ṣe Lé Wọn Síta!”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 9/1 ojú ìwé 32

“Má Ṣe Lé Wọn Síta!”

ÌWÉ agbéròyìnjáde náà, Corriere della Sera, gbani nímọ̀ràn pé: “Bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tàbí méjì pàápàá, bá tẹ aago ẹnu ọ̀nà rẹ, má ṣe lé wọn síta!” Ìwé agbéròyìnjáde náà ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó wáyé ní Treviso, àríwá Ítálì, nínú èyí tí ọkùnrin oníṣòwò kan ti fara wewu pípàdánù iye tí ó lé ní mílíọ̀nù kan owó lire (iye tí ó jú 600 dọ́là, U.S.) nítorí lílé àwọn Ẹlẹ́rìí méjì tí wọ́n ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀ dànù.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde náà ti sọ, àwọn Ẹlẹ́rìí méjì ṣe báyìí bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá ọkùnrin náà sọ pé: “Ọjọ́ ayọ̀ ni ọjọ́ òní jẹ́ fún ọ. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, a sì ní ohun iyebíye kan láti fún ọ.” Wọn kò tí ì sọ ọ́ tán, tí ọkùnrin oníṣòwò tí ń kanra gógó yìí fi pa ilẹ̀kùn rẹ̀ dé.

Ká ní ọkùnrin náà ti tẹ́tí sí wọn ni, ì bá ti mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí náà wá sí ilé rẹ̀ láti fún un ní àpamọ́wọ́ rẹ̀, tí wọ́n rí ní orí ìjókòó ibi ìgbafẹ́ ni. Nítorí náà, kò sí ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí náà lè ṣe ju kí wọ́n mú àpamọ́wọ́ náà àti ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá tí ó wà nítòsí. Ní ọjọ́ kejì, àwọn ọlọ́pàá mú un wá fún ẹni tí ó ni ín.

Ìwé ìròyìn náà, Il Gazzettino di Treviso, sọ pé: “Ká ní ẹlòmíràn ni àwọn [Ẹlẹ́rìí] tí ète wọn kò yọrí sí rere náà ni, ì bá ti . . . sọ àpamọ́wọ́ náà àti ohun tabua tí ń bẹ nínú rẹ̀ di tirẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ aláìlábòsí délẹ̀délẹ̀ kò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀.”

Kí ni ó sún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti jẹ́ “aláìlábòsí délẹ̀délẹ̀”? Ìfẹ́ wọn fún Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wọn ni, ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Jésù Kristi. (Mátíù 22:37-39) Ìdí rẹ̀ tún nìyẹn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń lọ láti ilé dé ilé láti polongo ìhìn rere nípa àgbàyanu “ilẹ̀ ayé tuntun” tí Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí. Irú ìhìn iṣẹ́ afúnninírètí bẹ́ẹ̀ ṣeyebíye fíìfíì ju ohun ini ti ara èyíkéyìí lọ!—Pétérù Kejì 3:13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́