“Ẹ̀bùn Àgbàyanu Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà”
ÌTẸ̀JÁDE Ilé-Ìṣọ́ná, May 1, 1996, ní ìjíròrò jíjinlẹ̀ nínú, ní ti àìdásí tọ̀tún tòsì Kristẹni, àti bí a ṣe lè mú kí ẹrù iṣẹ́ wa sí Jèhófà àti sí “Késárì” wà déédéé. (Mátíù 22:21) A ti gbọ́ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìmọrírì fún ìsọfúnni tuntun tí a pèsè. Nínú wọn ni lẹ́tà tí ó tẹ̀ lé e yìí, tí Ẹlẹ́rìí kan ní ilẹ̀ Gíríìsì kọ sí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé:
“Mo fẹ́ láti sọ ìmoore jíjinlẹ̀ mi jáde fún ẹ̀yin arákùnrin ọ̀wọ́n fún títọ́jú wa lọ́nà tí ó dára bẹ́ẹ̀ nípa tẹ̀mí. Níwọ̀n bí mo ti lo ọdún mẹ́sàn-án nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ Kristẹni mi, ní ti gidi, mo mọrírì àwọn ìrònú àgbàyanu tí ó wà nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà, May 1, 1996. (Aísáyà 2:4) Ẹ̀bùn àgbàyanu ni èyí jẹ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.—Jákọ́bù 1:17.
“Nígbà tí mo ń gbádùn àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí lọ́wọ́, mo rántí gbólóhùn kan nínú Ilé-Ìṣọ́nà kan nígbà kan rí (August 1, 1994, ojú ìwé 14): ‘Ní kedere, ìfòyebánilò jẹ́ ànímọ́ ṣíṣeyebíye, ọkàn tí ń sún wa láti túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jehofa síi.’ Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin arákùnrin, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé mo jẹ́ apá kan ètò àjọ rẹ̀ onínúure àti onífẹ̀ẹ́, tí ń fi ọgbọ́n rẹ̀ hàn ní kedere.—Jákọ́bù 3:17.
“A fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba ìmọ́lẹ̀ tí ó túbọ̀ mọ́lẹ̀ sí i nínú Ilé-Ìṣọ́nà May 1 níhìn-ín, ní ilẹ̀ Gíríìsì, ní pàtàkì láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n ti lo ọdún mélòó kan nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tàbí tí wọ́n ṣì wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ ṣeun o. Ǹjẹ́ kí Jèhófà máa fi ẹ̀mí rẹ̀ fún yín lókun, láti máa bá a nìṣó ní pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí tí ó níye lórí fún wa, ní àwọn àkókò onídààmú wọ̀nyí.”