ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 11/15 ojú ìwé 24
  • A Fìdí Ẹ̀tọ́ Ìjọ́hẹn Fún Ìtọ́jú Ìṣègùn Múlẹ̀ Lẹ́ẹ̀kan Sí I

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Fìdí Ẹ̀tọ́ Ìjọ́hẹn Fún Ìtọ́jú Ìṣègùn Múlẹ̀ Lẹ́ẹ̀kan Sí I
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 11/15 ojú ìwé 24

A Fìdí Ẹ̀tọ́ Ìjọ́hẹn Fún Ìtọ́jú Ìṣègùn Múlẹ̀ Lẹ́ẹ̀kan Sí I

ÌDÁJỌ́ kan tí Adájọ́ tí ó wà fún Àwọn Ìwádìí Ìbẹ̀rẹ̀ ní Ilé Ẹjọ́ ti Messina, Ítálì, kéde láìpẹ́, ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i pé àwọn dókítà gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ohun tí agbàtọ́jú kan tí ó tójúúbọ́ bá ń fẹ́ ní ti ìṣègùn. A gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ nínú ẹjọ́ kan tí ó kan ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ní January 1994, Antonino Stellario Lentini, Ẹlẹ́rìí kan tí ó jẹ́ ẹni ọdún 64, tí àrùn àsun-ùndá ẹ̀jẹ̀ ń yọ lẹ́nu ni a gbé lọ sí ilé ìwòsàn kan ní Taormina, Messina. Ìyàwó Antonino, Catena, sọ fún àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn pé, gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, òun àti ọkọ òun kì yóò jọ́hẹn fún ìtọ́jú onífàjẹ̀sínilára. (Ìṣe 15:20, 28, 29) A bọ̀wọ̀ fún ìfẹ́ inú wọn.

Ṣùgbọ́n, nígbà tí a ń gbé e lọ sí ibùdó ìtọ́jú ìlera mìíràn, Antonino kò lè mí dáradára mọ́, ó sì wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan sàréè. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó kú. Catena banú jẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n ó rí ìtùnú gíga nínú ìlérí Bíbélì nípa àjíǹde. (Ìṣe 24:15) Lẹ́yìn náà, sí ìyàlẹ́nu rẹ̀, àwọn adájọ́—tí ó ṣeé ṣe kí ìròyìn tí kò tọ́ tí ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde tàn kálẹ̀ ti ṣì lọ́nà—fẹ̀sùn fífa ikú ọkọ rẹ̀ kàn án, nítorí pé, ó kọ̀ fún àwọn dókítà láti ṣe iṣẹ́ abẹ tí wọ́n rí i pé ó pọn dandan fún un.

Lẹ́yìn ohun tí ó ju ọdún kan lọ, ní July 11, 1995, a dá Catena sílẹ̀, níwọ̀n bí kò ti hu ìwà ọ̀daràn kankan. Ní tòótọ́, ẹ̀rí àwọn ògbóǹkangí fi hàn pé, bí a bá gbé ipò aláìsàn náà yẹ̀ wò, lọ́nàkọnà ṣíṣiṣẹ́ abẹ fún un ì bá ti já sí òtúbáńtẹ́.

Ṣùgbọ́n gbólóhùn tí adájọ́ náà sọ, sọ ojú abẹ níkòó. Ó sọ pé, ó ṣòro láti tẹ́wọ́ gba èrò náà pé àwọn oníṣègùn ní láti dá sí ọ̀ràn nígbà tí aláìsàn tàbí ẹni tí ń ṣojú fún un bá kọ ìtọ́jú. Ó fi kún un pé, òfin ojúṣe ẹni ní ti ìṣègùn, tí ó jẹ́ ti ilẹ̀ Ítálì “rí i tẹ́lẹ̀ pé ó ṣe pàtàkì láti gba ìjọ́hẹn fún ìtọ́jú ìṣègùn ẹni tí ọ̀ràn kàn kí a tó ṣe ohunkóhun rárá.” Nípa báyìí, ó sọ pé Catena “lọ́nà tí ó bófin mu, dènà jíjẹ́ kí a lo irú ọ̀nà ìgbàtọ́jú bẹ́ẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”

Ìdájọ́ yìí fìdí ẹ̀tọ́ tí ẹnì kan tí ó tójúúbọ́ ní láti kọ ìtọ́jú ìṣègùn tí ó bá forí gbárí pẹ̀lú ìfẹ́ inú rẹ̀, múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́