ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 11/15 ojú ìwé 32
  • ‘Wọ́n Lọ́kàn Ìfẹ́ Nínú Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Wọ́n Lọ́kàn Ìfẹ́ Nínú Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 11/15 ojú ìwé 32

‘Wọ́n Lọ́kàn Ìfẹ́ Nínú Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́’

OHUN tí ọlọ́pàá kan ní New York City sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn. Kathleen, ọ̀kan lára àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni alákòókò kíkún, tí ń ṣiṣẹ́ sìn ni orílé-iṣẹ́ àgbáyé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà ní Brooklyn, New York, ni ó ń bá sọ̀rọ̀.

Ní ọjọ́ kan, ní àkókò tí ó ṣíwọ́ fún oúnjẹ ọ̀sán, nígbà ìwọ́wé tí ó móoru, tí oòrùn sì ń ràn yòò, Kathleen jókòó lórí bẹ́ǹṣì kan níbi Ìgbafẹ́ kan tí ó wà nítòsí. Ó ń tẹ́tí sí ẹ̀rọ tí ń lu kásẹ́ẹ̀tì tí ó ní gbohùngbohùn àtẹ̀bọtí. Ní ibùdó ọkọ̀ òfuurufú hẹlikọ́fítà tí ó wà ní òdì kejì East River, ìmúra ń lọ lọ́wọ́ fún póòpù, tí ó wá ṣe ìbẹ̀wò sí ìlú náà, láti gbéra lọ. Ààbò wà gbọn-in-gbọn-in níbi gbogbo, àwọn ọlọ́pàá kan sì ń lọ sókè sódò níbi Ìgbafẹ́ náà. Ọ̀kan lára wọn tọ Kathleen lọ, ó sì béèrè ohun tí ó ń ṣe. Kathleen fèsì pé: “Mo ń tẹ́tí sí ohùn àgbàsílẹ̀ lédè Rọ́ṣíà ni. Ṣé o rí i, mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì fẹ́ kọ́ èdè Rọ́ṣíà kí n baà lè ṣàjọpín ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè Rọ́ṣíà, tí wọ́n ń gbé ní ìlú yìí.”

Ọlọ́pàá náà fèsì pé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, òún ti wá gba ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọdún 15 sẹ́yìn tí òún ti fi jẹ́ òṣìṣẹ́ olóyè tí ń bójú tó ààbò ní New York City. Ó sọ pé: “Mo ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ìsìn tí ó wà létòlétò, tí àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ ní ọkàn-ìfẹ́ tòótọ́ nínú ríran àwọn ẹlòmíràn ládùúgbò lọ́wọ́.”

A mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé fún iṣẹ́ ìwàásù ẹnu-ọ̀nà-dé-ẹnu-ọ̀nà tí wọ́n ń ṣe. (Ìṣe 20:20) Nígbà tí wọ́n ń tọ́ka sí Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojútùú kan ṣoṣo sí àwọn ìṣòro tí ń pọ́n aráyé lójú, wọ́n tún ń ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mú ipò ìgbésí ayé wọn sunwọ̀n sí i nípa fífún wọn níṣìírí láti lo àwọn ìlànà Bíbélì nínú ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́. Fún àpẹẹrẹ, àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń rọ àwọn òbí láti pèsè àyíká inú ilé tí yóò mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ rọrùn. Wọ́n ń gba ẹnì kọ̀ọ̀kan níyànjú láti jẹ́ aláìlábòsí àti olùpòfinmọ́, ní fífún wọn níṣìírí láti ní àwọn òye iṣẹ́ àti ànímọ́ tí yóò wúlò fún agbanisíṣẹ́.

Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́kàn ìfẹ́ gidigidi nínú ríran àwọn ènìyàn tí ń bẹ láwùjọ lọ́wọ́ láti mú kí ìgbésí ayé wọ́n sunwọ̀n sí i. A fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà ké sí ọ láti dáhùn padà sí ìfilọni tí ó tẹ̀ lé e yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́