ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 12/1 ojú ìwé 32
  • Àwọn Wo Ni Yóò Jẹ́ Ajíhìnrere?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Wo Ni Yóò Jẹ́ Ajíhìnrere?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 12/1 ojú ìwé 32

Àwọn Wo Ni Yóò Jẹ́ Ajíhìnrere?

NÍBI ìpàdé kan tí Ìgbìmọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Àgbáyé ṣe ní nǹkan bí 40 ọdún sẹ́yìn, a rọ àwọn mẹ́ḿbà láti “mú ẹ̀mí ìjíhìnrere dàgbà” àti láti kọ́ agbo wọn láti “máa jíhìn rere.” Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, John A. O’Brien, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì kan, kọ̀wé nípa ìjẹ́pàtàkì mímú àwọn ọmọlẹ́yìn tuntun wá “nípa títọ̀ wọ́n lọ” kì í ṣe nípa wíwulẹ̀ “jókòó sínú ilé wa.” Ní January 1994, Póòpù John Paul Kejì wí pé “kì í ṣe àkókò láti tijú Ìhìn Rere, ó jẹ́ àkókò láti wàásù rẹ̀ láti orí òrùlé.”

Ó hàn gbangba pé, a ti kọ etí ikún sí àwọn ìkésíni lemọ́lemọ́ wọ̀nyí láti di ajíhìnrere. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé agbéròyìnjáde ti Illawarra Mercury wí pé: “Àwọn onísìn Kátólíìkì ti Gúúsù Bèbè Etíkun tí wọ́n yọrí ọlá kò hára gàgà láti ṣàmúlò ọ̀nà ìgbàjíhìnrere ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú ìsìn wọn.” Ọkùnrin kan wí pé ní ṣókí ìjíhìnrere “kì í ṣe apá kan ojú ìwòye ìsìn Kátólíìkì.” Ẹlòmíràn sọ pé: “Ó dára kí Ṣọ́ọ̀ṣì gbé ara rẹ̀ lárugẹ, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípasẹ̀ kíkan ilẹ̀kùn. Ó lè jẹ́ nípa ṣíṣètò àwọn ilé ẹ̀kọ́ tàbí kíkọ lẹ́tà ni yóò sàn jù.” Àní olórí kàtídírà àdúgbò kan kò mọ ohun tí yóò túmọ̀ ọ̀rọ̀ póòpù náà sí. Ó wí pé: “A óò rọ àwọn ènìyàn láti máa fi Ìhìn Rere tí wọ́n mọ̀ ṣèwàhù nínú ìgbésí ayé wọn. Bóyá ìyẹn túmọ̀ sí kíkan ilẹ̀kùn jẹ́ ohun mìíràn tí n kò ní fẹ́ mẹ́nu bà.” Àkọlé àpilẹ̀kọ ìròyìn náà ṣàkópọ̀ rẹ̀ dáradára pé: “Àwọn onísìn Kátólíìkì kì yóò kọbi ara sí àrọwà Póòpù láti wàásù.”

Láìka ìkùnà Kirisẹ́ńdọ̀mù láti jíhìn rere sí, iye tí ó ju mílíọ̀nù márùn-ún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù láti ‘lọ kí wọ́n sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.’ (Mátíù 28:19, 20; fi wé Ìṣe 5:42.) Ìwàásù wọn láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà ń lọ ní pẹrẹu nísinsìnyí ní èyí ti ó lé ní 230 ilẹ̀. Ìhìn iṣẹ́ tí wọ́n ń mú wá jẹ́ èyí tí ó bára dé, tí ń tẹnu mọ́ àwọn ìlérí àgbàyanu ti Bíbélì fún ọjọ́ ọ̀la. Èé ṣe tí o kò fi bá wọn sọ̀rọ̀ nígbà míràn tí wọ́n bá kàn sí ọ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́