Ta Ni Ó Ni Ẹ̀bi Ogun?
ỌLỌ́RUN ha ni ó ni ẹ̀bi ogun tí aráyé ti jà bí? “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Ọlọ́run kò fẹ́ ogun.” Bí Martin Niemöller, gbajú-gbajà àlùfáà ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì, ará Germany, ṣe dáhùn ìbéèrè yìí nìyẹn ní kété tí Ogun Àgbáyé Kejì dópin. A tẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ní 1946 nínú ìwé kan tí a pè ní Ach Gott vom Himmel sieh darein—Sechs Predigten (Ọlọ́run, Dákun Bojú Wolẹ̀ Láti Ọ̀run—Ìwàásù Mẹ́fà).a Ìwé náà sọ pé:
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti dá Ọlọ́run lẹ́bi [ogun] kò mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tàbí kò fẹ́ láti mọ̀ ọ́n. Àmọ́ ṣáá o, ọ̀ràn míràn ni ti pé bóyá àwa Kristẹni ni ó lẹ́bi jù lọ fún ogun tí kò dáwọ́ dúró tàbí àwa kọ́. A kò sì lè fi ìrọ̀rùn yẹ ìbéèrè yí sílẹ̀. . . . A tún lè rántí dáradára pé, jálẹ̀ ìtàn, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni ti yọ̀ǹda ara wọn láti gbàdúrà sórí ogun, ẹgbẹ́ ọmọ ogun, àti àwọn ohun ìjà ogun, tí wọ́n sì gbàdúrà lọ́nà tí kò bá ti Kristẹni mu rárá fún ìparun àwọn ọ̀tá wọn nínú ogun. Ẹ̀bi wa àti ti àwọn bàbá wa ni èyí, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò jẹ̀bi lọ́nàkọnà. Ó sì jẹ́ ìtìjú fún àwa Kristẹni òde òní láti dúró níwájú àwọn tí a rò pé wọ́n jẹ́ ẹ̀ya ìsìn irú bí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Onítara-Ọkàn [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà], tí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, [àní] tí wọ́n tilẹ̀ kú pàápàá nítorí pé wọ́n kọ ṣíṣiṣẹ́ sìn nínú ogun, wọ́n sì kọ̀ láti pa ènìyàn.”
Lónìí, nǹkan bí 50 ọdún lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn ọ̀rọ̀ Niemöller pèsè ohun kan fún àwọn ènìyàn onífẹ̀ẹ́ àlàáfíà láti ronú lé lórí. Bẹ́ẹ̀ kọ́, kì í ṣe Ọlọ́run ni ó ni ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tí àwọn orílẹ̀-èdè ta sílẹ̀! Ní tòótọ́, nípasẹ̀ àwọn olùjọsìn rẹ̀ tòótọ́, tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ìforígbárí ti ayé, Ọlọ́run ń polongo òpin tí ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí gbogbo ogun.—Orin Dáfídì 46:9; Jòhánù 17:16.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ àwọn ìwàásù Martin Niemöller jáde lẹ́yìn náà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì nínú ìwé náà, Of Guilt and Hope. Ṣùgbọ́n, ẹ̀dà ti èdè Gẹ̀ẹ́sì yàtọ̀ sí ẹ̀dà ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní èdè German, nítorí èyí, a túmọ̀ àyọlò yí ní tààràtà láti inú èdè German.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Fọ́tò USAF