ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 1/15 ojú ìwé 32
  • Gbogbo Wọn Ha Jẹ́ Ìṣípayá Àtọ̀runwá Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbogbo Wọn Ha Jẹ́ Ìṣípayá Àtọ̀runwá Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 1/15 ojú ìwé 32

Gbogbo Wọn Ha Jẹ́ Ìṣípayá Àtọ̀runwá Bí?

A HA lè sọ pé ẹ̀mí Ọlọ́run, tí ó mí sí Bíbélì Mímọ́, náà ni ó mí sí àwọn ìwé mìíràn tí àwọn kan kà sí ìwé mímọ́ bí? (Tímótì Kejì 3:16) Ìwé àtìgbàdégbà kan, tí ó jẹ́ ti àwọn ará Ítálì ẹlẹ́sìn Jesuit (La Civiltà Cattolica), tí a tẹ̀ jáde “lábẹ́ ìdarí Akọ̀wé Àgbà Ìjọba Àpapọ̀ ti [Vatican]” tí a sì gbà pé ó jẹ́ abẹnugan lágbo àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, ni ó gbé ìbéèrè yí dìde.

Ìwé àtìgbàdégbà tí ó jẹ́ ti àwọn ẹlẹ́sìn Jesuit wí pé: “Nípasẹ̀ ìṣiṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́, Ọlọ́run fọ́n irúgbìn Ọ̀rọ̀ náà ká sínú àwọn ìwé mímọ́ kan tí ó jẹ́ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí kì í ṣe ti àwọn Júù àti àwọn tí kì í ṣe ti Kristẹni.” Lójú àwọn ẹlẹ́sìn Jesuit, àwọn ìwé “mímọ́” irú bí Avesta ti Zoroaster tàbí Four Books ti Confucious, ni a kọ “lábẹ́ ìdarí Ẹ̀mí Mímọ́, nítorí náà, dé ìwọ̀n àyè kan, wọ́n ní ‘ìṣípayá àtọ̀runwá.’”

Ṣùgbọ́n, àpilẹ̀kọ náà mú un ṣe kedere. Ó wí pé: “Kì í ṣe gbogbo ohun tí ń bẹ nínú irú àwọn ìwé mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni ó jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” ní fífi kún un pé, àwọn tí wọ́n kọ àwọn ìwé wọ̀nyí ti lè “wà lábẹ́ agbára ìdarí àgbègbè tí a ti ń jọ́sìn ọ̀pọ̀ ọlọ́run tàbí ti ọlọ́gbọ́n èrò orí” tí wọ́n ń gbé, tí wọ́n sì ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Marco Politi, aṣojúkọ̀ròyìn àlámọ̀rí Vatican fún ìwé agbéròyìnjáde ti Ítálì La Repubblica, ti sọ, èrò yí “fàyè gba ohun tí à bá ti kà sí àjọṣepọ̀ tí kò ṣeé ṣe láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti àwọn ìsìn ńláńlá tí wọ́n gbajúmọ̀,” ní gbígbé ẹ̀mí ìpàdé àdúrà aláàmúlùmálà ìgbàgbọ́ dìde, irú èyí tí a rí ní Assisi ní 1986, tí John Paul Kejì gbé lárugẹ tagbáratagbára.

Jèhófà kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu àti ìdàrúdàpọ̀. (Kọ́ríńtì Kíní 14:33) Nítorí náà, kò tọ́ kí a parí èrò sí pé, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tàbí ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀, yóò tilẹ̀ mí sí apá kan àwọn ìwé èyíkéyìí tí kò bá Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, mu délẹ̀. Dípò fífún ìsọdọ̀kan nínú “òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ìsìn” tí ó yàtọ̀ síra níṣìírí, Kristẹni náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé, “ìrètí kan ṣoṣo . . . , Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan, ìbatisí kan” ní ń bẹ.—Éfésù 4:4, 5.

“Ìgbàgbọ́ kan” yẹn sinmi lórí lílo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi. Bíbélì sọ ọ́ lọ́nà ṣíṣe wẹ́kú pé: “Síwájú sí i, kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn, nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run tí a ti fi fúnni láàárín àwọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a gbọ́dọ̀ fi gbà wá là.” (Ìṣe 4:12) Kò sí “ìwé mímọ́” mìíràn tí ó fi Jésù hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni pàtàkì nínú mímú àwọn ète Ọlọ́run ṣẹ. Àfi bí a bá tẹ́wọ́ gba Bíbélì gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ó tó lè kọ́ wa nípa ète onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run pèsè fún ìgbàlà.—Jòhánù 17:3; Tẹsalóníkà Kíní 2:13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́