ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 2/1 ojú ìwé 8
  • Mímú Òtítọ́ Dé Ọ̀dọ̀ Onírúurú Ènìyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mímú Òtítọ́ Dé Ọ̀dọ̀ Onírúurú Ènìyàn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Bẹ́ẹ̀ Lẹ̀míi Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe Lágbára Tó Ni?
    Jí!—2002
  • Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Ẹ Máa Darí Ẹ
    Jí!—2014
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe?
    Jí!—2003
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Má Ṣe Fàyè Gba Ẹ̀mí Ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 2/1 ojú ìwé 8

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Mímú Òtítọ́ Dé Ọ̀dọ̀ Onírúurú Ènìyàn

ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù jẹ́ olùfìtara pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run. Kò jẹ́ kí àtakò dí iṣẹ́ tí a fàṣẹ yàn fún un láti wàásù “ìhìn rere” lọ́wọ́. (Kọ́ríńtì Kíní 9:16; Ìṣe 13:50-52) Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ẹlòmíràn láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.—Kọ́ríńtì Kíní 11:1.

A mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé fún ìsapá onípinnu wọn ní wíwàásù. Ní tòótọ́, wọ́n ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ ní “àsìkò tí ó rọgbọ” àti ní “àsìkò tí ó kún fún ìdààmú” láti ṣàṣeparí iṣẹ́ ‘sísọni di ọmọ ẹ̀yìn’ tí Ọlọ́run yàn wọ́n sí. (Tímótì Kejì 4:2; Mátíù 28:19, 20) Àní ní àwọn ilẹ̀ tí a ti ń ṣe àtakò sí wọn pàápàá, wọ́n ń mú ìhìn iṣẹ́ ṣíṣe pàtàkì jù lọ nípa Ìjọba Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ àwọn aláìlábòsí ọkàn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìrírí tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí ti ṣàkàwé.

◻ Ní erékùṣù kan ní ìwọ̀ oòrùn Pacific níbi tí iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà lábẹ́ ìfòfindè, ọmọdékùnrin ọlọ́dún 12 kan rí i pé ẹgbẹ́ búburú ni ó yí òun ká ní ilé ẹ̀kọ́. Ó jẹ́ àṣà ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní kíláàsì rẹ̀ láti máa mu sìgá, láti máa ka ìwé arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè, láti máa fìtínà àwọn olùkọ́, àti láti máa jà. Ipò náà burú débi pé ọmọdékùnrin náà bi bàbá rẹ̀ léèrè bí òun bá lè lọ sí ilé ẹ̀kọ́ mìíràn. Ṣùgbọ́n, bàbá náà bá ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ pé kí ó má ṣe bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí ó ti ronú pé ìwà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ yòó kù tí ń bẹ nítòsí kì yóò yàtọ̀. Síbẹ̀, báwo ni òun yóò ṣe ran ọmọkùnrin rẹ̀ lọ́wọ́?

Bàbá náà rántí pé òun ní ìwé kan fún àwọn ọ̀dọ́ nínú ilé. Ó jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ ìbátan kan tí ó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nítorí náà, ó wá ìwé náà, nígbà tí ó sì rí i, ó fún ọmọkùnrin rẹ̀. Àkọlé rẹ̀ ni Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́.a Ọmọdékùnrin náà rí i pé, orí náà, “Bawo Ni Mo Ṣe Lè Koju Ìkìmọ́lẹ̀ Ojúgbà?” ṣèrànwọ́ ní pàtàkì. Kì í ṣe kìkì pé ó kọ́ ọ ní ìjẹ́pàtàkì pípa ọ̀wọ̀ ara ẹni mọ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n, ó tún kọ́ ọ bí ó ṣe lè fi ọgbọ́n kọ̀ nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá gbìyànjú láti fi agbára mú un tọ ọ̀nà tí kò bọ́gbọ́n mu. Nípa fífi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tí ó rí nínú ìwé náà sílò, ọ̀dọ́kùnrin náà kọ́ bí ó ṣe lè ṣàṣeyọrí nínú kíkojú ìkìmọ́lẹ̀ ojúgbà.

Ní ṣíṣàkíyèsí ìwọ̀nyí àti àwọn ìyípadà rere mìíràn nínú ọmọkùnrin rẹ̀, bàbá náà pinnu láti ka ìwé náà. Bí ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tí ó rí nínú ìwé náà ti wú u lórí, bàbá náà béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, àwọn mẹ́ńbà míràn nínú ìdílé rẹ̀ dara pọ̀ mọ́ ọn nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Kí ni àbájáde rẹ̀? Ọmọdékùnrin náà, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin, bàbá rẹ̀, àti méjì lára àwọn òbí àgbà ọmọdékùnrin náà ti di mẹ́ńbà Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nísinsìnyí.

◻ Ní ilẹ̀ kan náà, a fi méjì lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n nítorí ìgbọràn tí wọ́n ń ṣe sí àwọn ìlànà Bíbélì láìgbagbẹ̀rẹ́. Ṣùgbọ́n, wọn kò jẹ́ kí ipò wọn fà wọ́n sẹ́yìn nínú fífi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n tọ ọ̀gá kan ní ọgbà ẹ̀wọ̀n lọ, wọ́n sì gba àṣẹ láti ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa níbẹ̀. Ẹ wo bí wọ́n ti láyọ̀ tó nígbà tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n 14 fí ọkàn ìfẹ́ hàn nínú Bíbélì, tí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí fún ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yí! Lẹ́yìn tí a dá wọn sílẹ̀, díẹ̀ lára wọn ń bá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti láti máa dara pọ̀ mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ní ohun tí ó ju ilẹ̀ 25, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jìyà nítorí ìfòfindè tàbí nítorí onírúurú àtakò tàbí inúnibíni. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn àpọ́sítélì, wọ́n ń bá a nìṣó “láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.”—Ìṣe 5:42.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́