Òtítọ́ Nípa Hẹ́ẹ̀lì
ÌRÒYÌN kan tí ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe lórí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì England gbé jáde sọ pé, hẹ́ẹ̀lì kì í ṣe iná ìléru mọ́; kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ibi àìsí ìgbòkègbodò. Ìròyìn náà ṣàlàyé pé: “Ọ̀pọ̀ ìdí wà fún ìyípadà yí. Ṣùgbọ́n lára wọn ni ìfẹ̀hónúhàn nínú àti lẹ́yìn òde ìsìn Kristẹni lọ́nà ìwà rere sí ìsìn kan tí ń gbin ìbẹ̀rù síni lọ́kàn, àti èrò tí ń gbèrú sí i pé èròǹgbà Ọlọ́run tí ń rán àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lọ sí ibi ìdálóro ayérayé yàtọ̀ pátápátá sí ìfẹ́ Ọlọ́run tí a ṣí payá nínú Kristi.”
Kì í ṣe Ṣọ́ọ̀ṣì England nìkan ni nǹkan kò fara rọ fún nípa èròǹgbà àtọwọ́dọ́wọ́ náà nípa hẹ́ẹ̀lì. Ó ń ṣòro fún àwọn ènìyàn láti inú onírúurú ẹ̀yà ìsìn láti jọ́sìn Ọlọ́run ẹ̀san tí ń jó àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ di eérú. Jackson Carroll, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìsìn àti àwùjọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìsìn ti Yunifásítì Duke sọ pé: “Àwọn ènìyàn ń fẹ́ Ọlọ́run tí ó jẹ́ oníyọ̀ọ́nú àti onífẹ̀ẹ́. Sísọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹ̀bi lòdì sí èrò ti òde òní.”
Tipẹ́tipẹ́ ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti gbà gbọ́ pé hẹ́ẹ̀lì, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti fi kọ́ni, wulẹ̀ jẹ́ isà òkú aráyé tí wọ́n ti kú—kì í ṣe ibi ìdálóró oníná. Wọ́n ní ojú ìwòye yìí, kì í ṣe nítorí pé ó gbajúmọ̀, ṣùgbọ́n nítorí ohun tí Bíbélì sọ pé: “Àwọn òkú kò mọ ohun kan . . . Kò sí ète, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n, ní isà òkú [“hẹ́ẹ̀lì,” Douay Version ti Kátólíìkì].”—Oníwàásù 9:5, 10.
Pẹ̀lú òye ṣíṣe kedere yìí nípa ipò tí àwọn òkú wà, Charles Taze Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Society, kọ̀wé tipẹ́tipẹ́ ní 1896 pé: “A kò rí irú ibi ìdálóró àìnípẹ̀kun bẹ́ẹ̀ [nínú Bíbélì] gẹ́gẹ́ bí ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ àti àwọn ìwé orin ìsìn, àti ọ̀pọ̀ ìwàásù, ti fi kọ́ni lọ́nà òdì. Síbẹ̀ a ti rí ‘hẹ́ẹ̀lì,’ ṣìọ́ọ̀lù, hédíìsì, tí a fi dá gbogbo ìran wa lẹ́bi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù, àti nínú èyí tí ikú Olúwa wa ti ra gbogbo wa pa dà; ‘hẹ́ẹ̀lì’ yẹn sì jẹ́ ibojì—ipò òkú.”
Nípa báyìí, fún ohun tí ó lé ní ọ̀rúndún kan, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fi òtítọ́ Bíbélì nípa hẹ́ẹ̀lì kọ́ni.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Charles T. Russell