Ta Ní Ń Darí Rẹ̀?
“TA NÍ ń ṣàkóso ayé?” Bí ẹnì kan bá bi ọ́ ní ìbéèrè yẹn, kí ni yóò jẹ́ èsì rẹ? Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn onísìn lè sọ pé “Ọlọ́run” tàbí “Jésù.” Àpilẹ̀kọ kan tí ó fara hàn nínú The Freeport News, ìwé ìròyìn ilẹ̀ Bahamas kan, sọ ìdáhùn kan tí ọ̀pọ̀ kò ní retí.
Ẹni tí ó kọ àpilẹ̀kọ náà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Mo rí ìwé àṣàrò kúkúrú kan ní ẹnu ọ̀nà mi. Lọ́pọ̀ ìgbà, n kì í ka irú ohun bẹ́ẹ̀ tí a bá fi há ẹnu ọ̀nà, ṣùgbọ́n mo pinnu láti kà á ní ọ̀tẹ̀ yí. Àkọlé rẹ̀ béèrè ìbéèrè náà, ‘Ta Ni Ń Ṣakoso Ayé Niti Tootọ?’” Nípa kíka ìwé àṣàrò kúkúrú tí a gbé karí Bíbélì náà, obìnrin yìí kẹ́kọ̀ọ́ pé, alákòóso ayé yìí kì í ṣe Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe Jésù, bí kò ṣe Sátánì Èṣù.—Jòhánù 12:31; 14:30; 16:11; Jòhánù Kíní 5:19.
Ìwé àṣàrò kúkúrú náà ṣàlàyé pé: “Gbe ìwà ailaanu yíyọyẹ́ ti o wà ninu ìwà òṣìkà buburu lékenkà yẹ̀ wo. Awọn eniyan ti lo awọn iyẹwu aláfẹ́fẹ́ aséniléèémí, awọn agọ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, awọn ohun ija afinásọ̀kò, awọn bọmbu onina, ati awọn ọna igbaṣe onika buruku jai miiran lati gba daniloro ati lati pa ẹnikinni keji ni ipakupa alailaanu. . . . Iru awọn agbara wo ni ń ti awọn eniyan sinu irufẹ awọn iṣe amúniwárìrì bẹẹ tabi ti ń dọgbọn dari wọn sinu awọn ipo nibi tí wọn ti ń nimọlara pe o pọndandan fun wọn lati hu awọn ìwà ìkà? Iwọ ha ti figbakanri ṣekayefi boya awọn agbara ibi, ti a kò le fojuri ni ń sún awọn eniyan lati hu iru awọn ìwà ipa bẹẹ bi?” Ó ha yani lẹ́nu pé Bíbélì pe Sátánì ní “ọlọ́run ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí” bí?—Kọ́ríńtì Kejì 4:4.
A láyọ̀ pé, àkókò tí Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kì yóò sí mọ́ ti sún mọ́ etílé. “Ayé ń kọjá lọ bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (Jòhánù Kíní 2:17) Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì ṣèlérí pé àwọn tí ó bá ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run ní ìrètí gbígbé títí láé nínú ayé tuntun òdodo kan. (Orin Dáfídì 37:9-11; Pétérù Kejì 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4) Ẹ wo irú ìtura tí yóò jẹ́ láti rí i kí a mú agbára ìdarí búburú Sátánì àti ti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò!
Lẹ́yìn ṣíṣàkópọ̀ ohun tí ó wà nínú ìwé àṣàrò kúkúrú yìí, ẹni tí ó kọ àpilẹ̀kọ ìwé ìròyìn The Freeport News náà dé ìparí èrò yí: “Mo dúpẹ́ pé mo ka ìwé àṣàrò kúkúrú yẹn . . . nítorí pé èmi pẹ̀lú ti ń ṣàníyàn nípa ipò inú ayé, àti nípa ẹni tí ń darí rẹ̀.”