ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 3/15 ojú ìwé 24
  • Bíbomi Paná Ẹ̀sùn Èké ní Ilẹ̀ Faransé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bíbomi Paná Ẹ̀sùn Èké ní Ilẹ̀ Faransé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 3/15 ojú ìwé 24

Bíbomi Paná Ẹ̀sùn Èké ní Ilẹ̀ Faransé

LÁÌPẸ́ yìí, a fi ọ̀pọ̀ ẹ̀sùn èké kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Faransé. Ní lílo àǹfààní àwọn ọ̀ràn ìbànújẹ́ tí ó kan àwọn ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ ìsìn ní Europe àti Japan, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn tan ìsọfúnni òdì kálẹ̀ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí. A fi wọ́n hàn lọ́nà òdì gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ tí ó tóbi jù lọ, tí ó sì léwu jù lọ.

Nínú ìsapá láti yanjú ọ̀ràn, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ ìwé àṣàrò kúkúrú kan jáde, tí ó dáhùn irú àwọn ìbéèrè wọ̀nyí bíi: Ta ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Kristẹni ha ni wọ́n bí? Wọ́n ha ń tẹ́wọ́ gba ìtọ́jú ìṣègùn bí? Èé ṣe tí wọ́n fi ń lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà? Báwo ni a ṣe ń bójú tó ìnáwó iṣẹ́ wọn? Àǹfààní wo ni àwùjọ ń jẹ lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Ìwé àṣàrò kúkúrú náà tí ó kún fún ìsọfúnni ní èdè Faransé ni a pè ní Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ohun Tí Ó Yẹ Kí O Mọ̀ Nípa Wọn. Kí a baà lè fi ìwé àṣàrò kúkúrú náà lé ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́wọ́ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó, a ṣètò ìgbétásì kan. Láti May 13 sí June 9, 1996, a pín ẹ̀dà tí ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn-án.

Ìwé àṣàrò kúkúrú yìí fa ọ̀pọ̀ lọ́kàn mọ́ra, títí kan àwọn lọ́gàá lọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba. Lẹ́yìn tí òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn kan ka ìwé àṣàrò kúkúrú náà tán, ó kọ̀wé pé: “Lámèyítọ́ tí a ṣe nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú inú bí mi. Lọ́pọ̀ ìgbà, mo ti mọrírì ìwà onínúure àti àìnímọ̀tara-ẹni-nìkan tí ẹ fi ń ṣiṣẹ́ yín.” Ní ìdáhùnpadà sí ìwé àṣàrò kúkúrú náà, mẹ́ńbà Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Ilẹ̀ Europe kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn mọ ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín ẹgbẹ́ Kristẹni ti ẹ̀yin jẹ́ apá kan rẹ̀ àti àwọn ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀.”

Ní Brittany, Ẹlẹ́rìí kan fi ìwé àṣàrò kúkúrú náà lọ àlùfáà kan, ẹni tí ó gbà á láìlọ́tìkọ̀. Àlùfáà náà wí pé: “Mo gbóṣùbà fún yín, nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe.” Ó fi kún un pé: “Mo fún àwọn ọmọ ìjọ mi níṣìírí láti gbà yín wọlé wọn, kí wọ́n sì fún yín ní ife kọfí. Ẹ tilẹ̀ lè sọ fún àwọn tí ẹ bá bá pàdé pé, ẹ ti dé ilé mi. Mo fẹ́ sọ fún yín pẹ̀lú pé, mo mọrírì kíka àwọn ìtẹ̀jáde yín.”

Lẹ́yìn gbígba ìwé àṣàrò kúkúrú náà, ọkùnrin onísìn Pùròtẹ́sítáǹtì kan ní Alsace kọ̀wé sí Watch Tower Society ní bíbéèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó kọ̀wé pé: “Lẹ́yìn sísọ gbogbo ìgbọ́kànlé nù nínú ṣọ́ọ̀ṣì mi, mo ń fojú sọ́nà fún ìbẹ̀rẹ̀ tuntun nípa tẹ̀mí.” Láìka àwọn ẹ̀sùn èké tí a fi ń kàn wọ́n nígbà míràn sí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ilẹ̀ Faransé—ní tòótọ́, ní gbogbo ayé—ń bá a nìṣó ní ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nípa ète Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí a ṣe là á sílẹ̀ nínú Bíbélì.—Tímótì Kejì 3:16, 17.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́