ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 6/15 ojú ìwé 32
  • “Ẹ Máa Sìnrú fún Ọ̀gá Náà, Kristi”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Máa Sìnrú fún Ọ̀gá Náà, Kristi”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 6/15 ojú ìwé 32

“Ẹ Máa Sìnrú fún Ọ̀gá Náà, Kristi”

JÁLẸ̀ ìtàn, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ti fara da ìnira ìsìnrú. Fún àpẹẹrẹ, ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jìyà gidigidi lọ́wọ́ àwọn alábòójútó tí wọ́n jẹ́ ọmọ Íjíbítì. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, wọ́n “yan àwọn akẹ́rúṣiṣẹ́ lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lórí láti mú kí ẹrù wíwúwo dẹ́rù pa wọ́n,” ní pàtàkì ní yíyọ bíríkì.—Ẹ́kísódù 1:11, The Jerusalem Bible.

Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lónìí, àwọn ènìyàn lè má sìnrú ní ti gidi, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ní láti ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí lábẹ́ ipò tí kò bára dé—nígbà míràn ó lè jẹ́ ipò líle koko. Wọ́n wà lábẹ́ ẹrù wíwúwo tí a lè pè ní ìsìnrú ti ọrọ̀ ajé.

Ṣùgbọ́n, oríṣi ìsìnrú kan wà tí kì í nini lára. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ máa sìnrú fún Ọ̀gá náà, Kristi.” (Kólósè 3:24) Àwọn tí wọ́n yàn láti di ẹrú Kristi ń rí ìtura láti inú ẹrù wíwúwo tiwọn. Jésù fúnra rẹ̀ wí pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn àyà ni èmi, ẹ̀yin yóò sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere ẹrù mi sì fúyẹ́.”—Mátíù 11:28-30.

Gbígba àjàgà Kristi sọ́rùn kò ní kí ẹnì kan má ṣe ojúṣe rẹ̀ láti pèsè nípa ti ara fún ìdílé rẹ̀. (Tímótì Kíní 5:8) Ṣùgbọ́n, ó pèsè òmìnira kúrò lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ ìdẹkùn ìlépa ọrọ̀ àlùmọ́nì. Dípò sísọ ìtura tí ohun ìní ti ara ń mú wá di olórí góńgó wọn nínú ìgbésí ayé, àwọn Kristẹni ń jẹ́ kí àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé tẹ́ wọn lọ́rùn.—Tímótì Kíní 6:6-10; fi wé Kọ́ríńtì Kíní 7:31.

Àwọn Kristẹni tún ń rí ìtura nínú ṣíṣe ojúṣe wọn ní ti wíwàásù “ìhìn rere” Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) Èyí ń mú ojúlówó ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn wá!

Ó yẹ kí a kún fún ọpẹ́ pé a lè “sìnrú fún Ọ̀gá náà, Kristi”!

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́