Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Ó Rí “Péálì Kan Tí Ìníyelórí Rẹ̀ Ga”
“ÌJỌBA àwọn ọ̀run . . . dà bí olówò arìnrìn-àjò kan tí ń wá àwọn péálì àtàtà. Nígbà tí ó rí péálì kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga, ó jáde lọ ó sì ta gbogbo ohun tí ó ní ní kánmọ́kánmọ́ ó sì rà á.” Pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Jésù ṣàkàwé ìníyelórí gíga lọ́lá tí Ìjọba Ọlọ́run ní. (Mátíù 13:45, 46) Àwọn tí wọ́n mọ ìníyelórí Ìjọba náà sábà máa ń fara wọn rúbọ lọ́nà gíga lọ́lá kí ọwọ́ wọn baà lè tẹ̀ ẹ́. Èyí ni ìrírí tí ó tẹ̀ lé e yìí láti Pingtung County, Taiwan, ṣàkàwé.
Ní ọdún 1991, Ọ̀gbẹ́ni àti Ìyáààfin Lin bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí àlùfáà àdúgbò kan gbọ́ nípa rẹ̀, ó gbìyànjú láti mú kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ ṣọ́ọ̀ṣì òun. Níwọ̀n bí òwò títa ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ àti pẹ́pẹ́yẹ ní ọjà àdúgbò ti jẹ́ òwò ìdílé Lin, wọ́n pinnu láti béèrè ojú ìwòye àlùfáà náà lórí ọ̀ràn náà. Ó fèsì pé: “Gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá ni ènìyàn lè jẹ.” Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí fún wọn níṣìírí láti gbé ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ yẹ̀ wò. Wọ́n kọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run ka ẹ̀jẹ̀ sí ohun ọlọ́wọ̀, nítorí “ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá.” (Léfítíkù 17:10, 11, The New English Bible) Nítorí náà, àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ “takété sí . . . ẹ̀jẹ̀.” (Ìṣe 15:20) Ìyọrísí ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lórí kókó ẹ̀kọ́ yìí ni pé, ìdílé Lin pinnu láti dẹ́kun títa ẹ̀jẹ̀, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ ibi tí owó ti ń wọlé jù lọ fún wọn. Ṣùgbọ́n, láàárín àkókò díẹ̀, wọ́n dojú kọ ìdánwò tí ó tún ga ju èyí lọ.
Ṣáájú kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ìdílé Lin gbin 1,300 ọ̀pẹ betel sórí ilẹ̀ wọn. Bí yóò tilẹ̀ gba ọdún márùn-ún kí àwọn igi wọ̀nyí tó lè máa mówó wọlé, gbàrà tí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í so, Ọ̀gbẹ́ni àti Ìyáààfin Lin lè retí 77,000 dọ́là lọ́dọọdún. Bí ìgbà ìkórè àkọ́kọ́ ti ń sún mọ́lé, ìdílé Lin ní láti ṣe ìpinnu pàtàkì. Wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ wẹ ara wọn mọ́ kúrò nínú “gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí” nípa yíyẹra fún irú ìwà ẹ̀gbin bíi sìgá mímu, ìjoògùnyó, àti jíjẹ ẹ̀pà betel tàbí gbígbé irú ìwà bẹ́ẹ̀ lárugẹ. (Kọ́ríńtì Kejì 7:1) Kí ni wọn yóò ṣe?
Nítorí tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ń yọ ọ́ lẹ́nu, Ọ̀gbẹ́ni Lin pinnu láti pa ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tì. Láàárín àkókò náà, Ìyáààfin Lin ta ẹ̀pà betel tí ó rí lára díẹ̀ nínú oko ọ̀pẹ betel tí wọ́n ti gbìn tẹ́lẹ̀, èrè tí ó rí sì lé ní 3,000 dọ́là. Èyí wulẹ̀ jẹ́ ìtọ́wò lásán fún ohun tí yóò máa wọlé wá láìpẹ́ bí wọ́n bá ń tọ́jú àwọn igi náà. Ṣùgbọ́n, ẹ̀rí ọkàn Ọ̀gbẹ́ni Lin ṣì ń nà án lọ́rẹ́.
Ó bá ọ̀ràn yí yí títí ọjọ́ kan, tí ó ní kí Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń bẹ ládùúgbò bá òun gé àwọn ọ̀pẹ betel náà lulẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣàlàyé pé òun ni yóò ṣe ìpinnu yẹn; nítorí náà, òun ni yóò ‘ru ẹrù ara rẹ̀’ tí yóò sì fọwọ́ ara rẹ̀ gé àwọn igi náà lulẹ̀. (Gálátíà 6:4, 5) Wọ́n fún un níṣìírí láti rántí ìlérí tí ó wà nínú Kọ́ríńtì Kíní 10:13, tí ó sọ pé: “Kò sí ìdẹwò kankan tí ó ti ba yín bí kò ṣe ohun tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, òun kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò rékọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n papọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè faradà á.” Àwọn Ẹlẹ́rìí tún fọ̀rọ̀ lọ ìrònú rẹ̀, ní sísọ pé: “Bí a bá bá ọ gé igi rẹ lulẹ̀, o lè kábàámọ̀ rẹ̀, kí o sì dá wa lẹ́bi fún ohun tí o pàdánù.” Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ariwo ẹ̀rọ ayùn jí Ìyáààfin Lin sílẹ̀. Ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ ń gé àwọn ọ̀pẹ betel náà lulẹ̀!
Ọ̀gbẹ́ni Lin rí i pé Jèhófà ń mú ìlérí Rẹ̀ ṣẹ. Ó rí iṣẹ́ kan tí kò da ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ láàmú, tí ó mú kí ó ṣeé ṣe fún un láti di olùyin Jèhófà. Ó ṣe ìrìbọmi ní àpéjọ àyíká ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní April 1996.
Bẹ́ẹ̀ ni, Ọ̀gbẹ́ni Lin ní ti gidi “ta gbogbo ohun tí ó ní,” ó sì ra “péálì kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga.” Nísinsìnyí, ó ní àǹfààní aláìṣeédíyelé ti níní ipò ìbátan pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run àti ṣíṣiṣẹ́ sin ire Ìjọba Rẹ̀.