Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ti Connecticut Gbé Ẹ̀tọ́ Aláìsàn Lárugẹ
Ní April 16, 1996, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Connecticut, U.S.A., gbé ẹ̀tọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti kọ ìfàjẹ̀sínilára sílẹ̀ lárugẹ. Ìdájọ́ yìí yí ìpinnu ìgbẹ́jọ́ àkọ́kọ́ pa dà.
Ní August 1994, ẹ̀jẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya lára Nelly Vega, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lẹ́yìn tí ó bí ọmọ rẹ̀ àkọ́kọ́. Ìsapá láti dá ẹ̀jẹ̀ tí ń ya lára rẹ̀ dúró já sí pàbó. Bí ipò Ìyáàfin Vega ti ń burú sí i, ilé ìwòsàn náà wá ọ̀nà láti gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ ilé ẹjọ́ láti fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára. Ìyáàfin Vega ti fọwọ́ sí ìwé tí ó tú àwọn dókítà sílẹ̀, tí ó sọ pé, a kò gbọ́dọ̀ fún òun ní ẹ̀jẹ̀ tàbí ohun tí a fi ẹ̀jẹ̀ ṣe, ní gbogbo ìgbà tí ó fi máa wà ní ilé ìwòsàn, tí ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ yọ ẹ̀bi èyíkéyìí kúrò lọ́rùn ilé ìwòsàn náà fún àbájáde ìpinnu rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ilé ìwòsàn náà jiyàn pé, fífipá fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára yóò jẹ́ fún ire ìkókó náà tí yóò nílò ìyá rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ilé ìwòsàn náà ti sọ. Ilé ẹjọ́ náà tún ṣàníyàn pé, yátọ̀ sí pé Ìyáàfin Vega ti pàdánù ẹ̀jẹ̀, ó ṣì jẹ́ ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ adélébọ̀, tí ìlera rẹ̀ jí pépé. Nítorí náà, láìka pé ọkọ Ìyáàfin Vega àti agbẹjọ́rò rẹ̀ kò fọwọ́ sí i, ilé ẹjọ́ náà fọwọ́ sí ìbéèrè náà, wọ́n sì fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára.
Bí ọjọ́ ti ń lọ, a gbé ẹjọ́ náà wá síwájú Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Connecticut. Níbẹ̀, gbogbo wọn láìku ẹni kan gbà pé ìgbésẹ̀ ilé ìwòsàn náà fi ẹ̀tọ́ Ìyáàfin Vega dù ú. Ìdájọ́ náà kà pé: “Ìgbẹ́jọ́ níwájú ilé ẹjọ́ náà wáyé ní ọ̀gànjọ́ òru, nínú ipò pàjáwìrì gan-an, tí kò fún ẹgbẹ́ méjèèjì ní àǹfààní tí ó pọ̀ tó láti múra ọ̀ràn wọn sílẹ̀ dáradára.”
Ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Connecticut ṣe yìí ṣe pàtàkì fún àwọn ẹlòmíràn yàtọ̀ sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Donald T. Ridley, agbẹjọ́rò Ìyáàfin Vega sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì fún gbogbo aláìsàn, tí wọ́n lè má fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ìpinnu dókítà wọn. Ìdájọ́ náà yóò ṣèdíwọ́ fún àwọn ilé ìwòsàn láti lo agbára lórí ìlànà tí aláìsàn náà dì mú, yálà ní ti ìsìn tàbí èyí tí kì í ṣe ti ìsìn.”