Fífa “Omi Jíjìn” Jáde
ÒWE Bíbélì kan sọ pé: “Ìmọ̀ nínú ọkàn ènìyàn dà bí omi jíjìn; ṣùgbọ́n amòye ènìyàn ní í fà á jáde.” (Òwe 20:5) Ní àkókò tí a kọ Bíbélì, ó ṣòro gidigidi láti rí omi ju bí ó ti rí ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ lónìí. Nígbà tí Jésù bá obìnrin ará Samáríà sọ̀rọ̀, ó ń fa omi láti inú ìsun omi Jékọ́bù, kànga kan tí ó jìn tó mítà 23!—Jòhánù 4:5-15.
Gẹ́gẹ́ bí Òwe 20:5 ti fi hàn, ìfòyemọ̀ tí a nílò láti fa èrò àti ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ tí ẹnì kan fi pa mọ́ sínú ọkàn àyà rẹ̀ jáde dà bí ìsapá tí fífa omi jáde láti inú kànga ń béèrè. Èyí jẹ́ òtítọ́ ní ọ̀pọ̀ jù lọ apá ìgbésí ayé. Fún àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kí o mọ àwọn kan tí wọ́n ti kó ìmọ̀ àti ìrírí jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Bí àwọn wọ̀nyí kò bá nítẹ̀sí láti fínnúfíndọ̀ fúnni ní ìmọ̀ràn tí a kò béèrè fún, o lè ní láti fa ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu wọn. Nípa fífìfẹ́hàn, bíbèèrè ìbéèrè, àti fífi ọgbọ́n fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò, ìwọ yóò máa ju doro rẹ sínú kànga jíjìn ti ọgbọ́n, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀.
Ìmọ̀ràn inú Òwe 20:5 ṣeé mú lò nínú ìdílé pẹ̀lú. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń gbọ́ tí àwọn aya máa ń sọ pé: “Ọkọ mi kì í sọ ìmọ̀lára rẹ̀ jáde fún mi!” Ọkọ kan lè sọ pé: “Aya mi kò tilẹ̀ bá mi sọ̀rọ̀ rárá!” Nínú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, ó ń béèrè ìfòyemọ̀ láti fa èrò tí ó jinlẹ̀ nínú ọkàn àyà alábàá-ṣègbéyàwó ẹni jáde. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ìbéèrè ọlọgbọ́n (Ṣé òní kò le? Kí ní ṣẹlẹ̀? Ìrànlọ́wọ́ wo ni mo lè ṣe?) máa ń mú kí a tú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀ sílẹ̀. Fífi irú ìfòyemọ̀ bẹ́ẹ̀ hàn yóò fún ìdè ìgbéyàwó lókun, sí ire ọkọ àti aya.