Àìróorunsùn Tí Ó Mú Àǹfààní Wá
ÀWỌN ọba pàápàá máa ń ṣàìróorunsùn. Olùṣàkóso Páṣíà kan, tí a kò lè kóyán rẹ̀ kéré ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa, Ahasuwérúsì, ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀. Bóyá ó ń rò pé òun ti pa àwọn ojúṣe kan tì, ó ní kí a ka àkọsílẹ̀ àwọn ọba sí òun létí. Ó gbọ́ pé olóòótọ́ ìránṣẹ́ kan, Módékáì, ti dojú ọ̀tẹ̀ ìyọ́kẹ́lẹ́pani lójijì kan délẹ̀ rí, tí a kò sì tí ì san èrè kankan fún un. Ahasuwérúsì pinnu láti wá nǹkan ṣe sí ìgbójúfòdá yìí kíákíá. Àǹfààní tí ìgbésẹ̀ rẹ̀ mú bá àwọn ènìyàn Ọlọ́run fi hàn pé Ọlọ́run ni ó fa àìróorunsùn ọba náà.—Ẹ́sítérì 6:1-10.
Ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú etíkun Hermanus ti Gúúsù Áfíríkà ní ìdí láti rántí apá yìí nínú Bíbélì. Inú gbọ̀ngàn kan tí wọ́n háyà ni wọ́n ti máa ń pàdé. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n ti gbìyànjú láti ra ilẹ̀ tí wọn yóò kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tiwọn sí. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ní ọdún 1991, Ìgbìmọ̀ Elétò Ìlú fi ilẹ̀ kan tí ó jọjú lọ̀ wọ́n.
Àmọ́, àwọn kan ta ko títa ilẹ̀ yí fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn ìdádúró fún ọ̀pọ̀ oṣù, a fi tó ìjọ náà létí pé àṣẹ ọlọ́dún mẹ́ta kan ti jáde pé a kò gbọ́dọ̀ ta ilẹ̀ náà fún ṣọ́ọ̀ṣì, wọn kò sì gbà láti ta ilẹ̀ náà fún wọn mọ́. Ní May ọdún 1993, ìjọ tún pa dà kọ lẹ́tà, ní rírọ ìgbìmọ̀ náà láti tún ìpinnu wọn gbé yẹ̀ wò. Lẹ́tà onígbólóhùn kan ṣoṣo ni èsì tí wọ́n rí gbà, tí ó sọ pé àṣẹ náà ṣì múlẹ̀.
Ní October ọdún yẹn, ọ̀kan lára àwọn káńsílọ̀ ìlú náà kò rí oorun sùn lóru. Obìnrin náà lo gbogbo àkókò náà láti yẹ àwọn ìwé ìpàdé tí ìgbìmọ̀ náà ti ṣe sẹ́yìn wò láti rí bóyá ọ̀ràn kankan wà tí ó ń fẹ́ àfiyèsí. Lẹ́tà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí kọ tí wọ́n fi rọ ìgbìmọ̀ náà láti tún ìpinnu rẹ̀ gbé yẹ̀ wò gba àfiyèsí rẹ̀. Nípa báyìí, ó pinnu láti fi ọ̀ràn náà sára kókó ìjíròrò fún ìpàdé tí wọn yóò ṣe tẹ̀ lé e. Ó fẹ́ tọ́ka sí i pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ̀wé béèrè fún ilẹ̀ náà ṣáájú kí a tó gbé àṣẹ tí a fi gbẹ́sẹ̀ lé títa ilẹ̀ náà fún ṣọ́ọ̀ṣì jáde.
Kò pẹ́ kò jìnnà, a fún ìjọ náà ní ilẹ̀ kan náà tí a ti kọ́kọ́ fi lọ̀ wọ́n ní ọdún 1991! Ẹ̀gbẹ́ òpópónà ni ó wà, ó sì sún mọ́ àgbègbè àwọn mẹ́ńbà ìjọ àti àwọn olùfìfẹ́hàn. Wọ́n ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba rèǹtè rente kan síbẹ̀ báyìí, a sì yà á sí mímọ́ fún Jèhófà ní October 5, 1996.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọ bá káńsílọ̀ náà káàánú fún ìnira àìróorunsùn, òtítọ́ náà pé Ọba Ahasuwérúsì ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀ lè tù ú nínú. Àbájáde ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì sì mú àǹfààní wá. Inú ìjọ tí ó wà ní Hermanus dùn jọjọ láti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tiwọn, ojúkò fún ìjọsìn mímọ́ gaara àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ ti ìṣàkóso Ọlọ́run ní ìlú etíkun lílókìkí yìí.—Hébérù 10:24, 25.