Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Àwọn Ọ̀dọ́ Yin Ọlọ́run ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Congo
NÍ Ọ̀PỌ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, onísáàmù náà fi ọ̀yàyà ké sí àwọn ọ̀dọ́ láti dara pọ̀ nínú yíyin Ọba ayérayé: “Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin àti ẹ̀yin wúńdíá pẹ̀lú, ẹ̀yin arúgbó pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yin ọmọdékùnrin . . . , yin orúkọ Jèhófà, nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ṣoṣo ni ó ga ré kọjá ibi tí ó ṣeé dé.” (Orin Dáfídì 148:12, 13, NW) Àwọn ìrírí tí ó tẹ̀ lé e láti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Congo tẹnu mọ́ àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ yìí.
• Ìwà Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wú onílé aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kan lórí. Nítorí èyí, ó yọ̀ǹda kí Àwọn Ẹlẹ́rìí máa bá Fifi, ọmọbìnrin rẹ̀ ọlọ́dún márùn-ún, kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn kíkíyèsí ìtẹ̀síwájú Fifi nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Iwe Itan Bibeli Mi,a bàbá rẹ̀ yọ̀ǹda fún un láti lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Níbẹ̀, Fifi kékeré kọ́ àwọn orin Ìjọba láti inú ìwé orin Àwọn Ẹlẹ́rìí. Ó yan orin nọnba 4, tí àkọlé rẹ̀ sọ pé, “Ileri Ọlọrun fún Paradise,” láàyò.
Ní ọjọ́ kan, bàbá Fifi pinnu láti mú un lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀. Sí ìyàlẹ́nu gbogbo ènìyàn, Fifi kọ̀ láti kọ àwọn orin ṣọ́ọ̀ṣì. Èé ṣe? Nítorí tí ó ronú pé àwọn orin tí wọ́n ń kọ ní ṣọ́ọ̀ṣì bàbá òun kò sí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí ó ti kọ́ láti inú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀. Tìgboyàtìgboyà, ó kọ orin Ìjọba tí ó yàn láàyò dípò rẹ̀.
Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ìgbìdánwò wọn láti mú kí ó yí èrò rẹ̀ pa dà já sí pàbó, àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì náà pinnu láti yọ Fifi, ọmọ ọlọ́dún márùn-ún náà, lẹ́gbẹ́! Láìka ìwà ìkà yí sí, bàbá rẹ̀ pa rọ́rọ́. Dídì tí Fifi di ìdúró rẹ̀ mú ṣinṣin fún ohun tí ó gbà gbọ́ wú u lórí gidigidi. Bàbá àti ìyá Fifi fẹ́ kí ó máa bá a lọ ní kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
• Nígbà tí ọmọkùnrin ọ̀dọ́langba kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lukodi, pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bàbá rẹ̀ ta kò ó gidigidi. Nígbà kan, nígbà tí Lukodi ń múra àtilọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, bàbá rẹ̀ fi àdá halẹ̀ mọ́ ọn. Nígbà míràn, bàbá Lukodi la igi mọ́ ọn, ó sì dá ọgbẹ́ ńlá sí i lẹ́yìn. Láìka àtakò líle koko náà sí, Lukodi rọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ̀ láti di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ń bá a lọ láti tẹ̀ síwájú, ó sì ṣe ìrìbọmi. Ó ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé nísinsìnyí.
Ìdúró Lukodi wú Sona, àbúrò rẹ̀, lórí gidigidi débi pé òun náà bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣùgbọ́n, láti dí i lọ́wọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́, bàbá wọn rán Sona lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ní abúlé mìíràn, níbi tí kò sí Àwọn Ẹlẹ́rìí. Síbẹ̀síbẹ̀, Sona sọ ọ́ di àṣà láti sọ nípa àwọn ohun tí ó ti kọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìfẹ́ hàn.
Nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí láti abúlé kan nítòsí gbọ́ nípa ìgbòkègbodò ìwàásù Sona, wọ́n ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ṣètò fún un láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé déédéé. Ó ń bá a lọ láti tẹ̀ síwájú, kò sì pẹ́ tí ó fi dara pọ̀ mọ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí tí ó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, tí ó sì ti ṣèrìbọmi. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní báyìí, mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ti di akéde tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi, a sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ ní abúlé yìí.
Ẹ wo bí ó ti jẹ́ àgbàyanu tó, bí ó sì ti tuni lára tó nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ bá dara pọ̀ nínú yíyin orúkọ Jèhófà!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.