ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 1/1 ojú ìwé 32
  • Ọ̀rọ̀ Pèsì Jẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Pèsì Jẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 1/1 ojú ìwé 32

Ọ̀rọ̀ Pèsì Jẹ

ÌWÉ agbéròyìnjáde Roman Kátólíìkì ti ilẹ̀ Britain, Catholic Herald, gbé lẹ́tà tí ó tẹ̀ lé e yìí jáde láti ọ̀dọ̀ òǹkàwé kan ní Wales, lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé: “Ní alẹ́ ọjọ́ kan, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wá sí ẹnu ilẹ̀kùn mi. Mo gbìyànjú láti sọ pé Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ni ó fìdí ìjótìítọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n fà yọ nínú Májẹ̀mú Tuntun náà múlẹ̀. Sí ìyàlẹ́nu mi, ọ̀kan nínú wọ́n gbà pẹ̀lú mi. Ó sọ pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ fìdí ìjótìítọ́ rẹ̀ múlẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò tẹ̀ lé e. Jésù sọ pé, “ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kíní kejì gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín,” ṣùgbọ́n ẹ ń pa ara yín lẹ́nì kíní kejì. Nínú ogun tí ó kọjá, àwọn Kátólíìkì pa Kátólíìkì, ṣùgbọ́n kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà èyíkéyìí tí ó pa Ẹlẹ́rìí [ẹlẹgbẹ́ rẹ̀].’ Kí ni ǹ bá ṣe ju pé kí n gbà pẹ̀lú rẹ̀? Báwo ni a ṣe lè gbàdúrà fún wíwà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ‘àwọn arákùnrin wa tí ó yapa’ nígbà tí kò sí ìṣọ̀kan tòótọ́ láàárín àwa fúnra wa? Kò ha yẹ kí a kọ́kọ́ ṣàtúnṣe ìtìjú burúkú yìí?”—Jòhánù 15:12.

Àwọn ogun àgbáyé méjì tí ó wáyé ní ọ̀rúndún ogún yìí bẹ̀rẹ̀ láàárín Kirisẹ́ńdọ̀mù, ó sì gba ẹ̀mí tí ó tó nǹkan bí 50 sí 60 mílíọ̀nù. Ṣùgbọ́n, a lè sọ ní tòótọ́ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò kópa kankan nínú àwọn ogun wọ̀nyẹn, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò lọ́wọ́ nínú àwọn ìforígbárí tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́. Báwo ni èyí ṣe ṣeé ṣe? Yóò jẹ́ fún àǹfààní rẹ láti ṣèwádìí síwájú sí i nípa ìdè lílágbára ti ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan Kristẹni tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún ní kárí ayé.—Fi wé Aísáyà 2:4.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Fọ́tò U.S. National Archives

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́