Kí Ní Ń sún Wọn Ṣe é?
NÍ ỌDỌỌDÚN, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń péjọ lẹ́gbẹẹgbẹ̀rún ní àwọn àpéjọpọ̀ wọn. Níbẹ̀, wọ́n ń gbádùn ìfararora, wọ́n sì ń tẹ́tí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìtọ́ni pípinminrin láti inú Bíbélì. Ó gba ìsapá gidigidi fún àwọn kan láti lè lọ sí àwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí. Fún àpẹẹrẹ, ní èṣí, ní Màláwì, tọkọtaya kan tí wọ́n ti lé ní ẹni ọgọ́ta ọdún pẹ̀lú ọmọkùnrin wọn àti aya rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ jòjòló, rìnrìn àjò 80 kìlómítà lórí kẹ̀kẹ́ ológeere, láti lọ sí àpéjọpọ̀. Wọ́n fi abúlé wọn sílẹ̀ ní agogo mẹ́fà òwúrọ̀, wọ́n sì dé ilẹ̀ àpéjọpọ̀ ní wákàtí 15 lẹ́yìn náà.
Ní Mòsáńbíìkì, àwùjọ kan rìnrìn àjò lórí kẹ̀kẹ́ ológeere fún ọjọ́ mẹ́ta, láti lè dé àpéjọpọ̀. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ìta gbangba ni wọ́n pàgọ́ sí, ní alẹ́ ọjọ́ kan, wọ́n gbọ́ tí àwọn kìnnìún ń bú ramúramù nítòsí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ju igi ìdáná sí ibi tí wọ́n ti ń gbúròó àwọn ẹranko náà, àwọn kìnnìún náà kò lọ títí ilẹ̀ fi mọ́. Ẹlẹ́rìí mìíràn tí ó ń rìnrìn àjò lọ sí àpéjọpọ̀ kan náà pàdé kìnnìún lójú ọ̀nà. Ó rọra dúró jẹ́ẹ́ láìmira títí tí kìnnìún náà fi bá tirẹ̀ lọ. Ní àpéjọpọ̀ náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí fi tayọ̀tayọ̀ ròyìn bí a ti ‘dá wọn nídè kúrò lẹ́nu kìnnìún.’—2 Tímótì 4:17.
Ọ̀pọ̀ lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá gidigidi láti pésẹ̀ sí àwọn àpéjọpọ̀ tàbí àwọn ìpàdé ìjọ tí a ń ṣe ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ fún ìjọsìn pàápàá. Èé ṣe? Àwọn àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí pípéjọpọ̀ fi ṣe pàtàkì gidigidi tó bẹ́ẹ̀.