Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà Fún Ilẹ̀ Ayé Wa?
Ìwé náà, World Military and Social Expenditures 1996 sọ pé: “Kò sí ọ̀rúndún mìíràn nínú ìtàn tí ó burú tó ọ̀rúndún ogún nínú híhu ìwà ipá tí ó luko nígboro, nínú iye ogun jíjà, àti iye owó gọbọi tí a ná sórí ‘ìgbèjà.’” Ipò yìí yóò ha yí padà láé bí?
Àpọ́sítélì Pétérù rán àwọn Kristẹni létí nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú, pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí [Ọlọ́run], nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Aísáyà ni ó kọ́kọ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. (Aísáyà 65:17; 66:22) Ísírẹ́lì ìgbàanì rí ìmúṣẹ rẹ̀ àkọ́kọ́ nígbà tí a mú orílẹ̀-èdè náà padà bọ̀ sí ilẹ̀ tí a ṣèlérí fún un lẹ́yìn tí ó lọ sí oko òǹdè ní Bábílónì fún 70 ọdún. Nípa sísọ àsọtúnsọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun,” Pétérù fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ náà yóò ṣì ní ìmúṣẹ tí ó gbòòrò ju ti tẹ́lẹ̀ pàápàá—ìmúṣẹ kárí ayé!
Ìdásílẹ̀ ipò òdodo ní gbogbo ilẹ̀ ayé jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, a ó sì mú un ṣẹ nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ọ̀run, níbi tí Kristi yóò ti jẹ́ Ọba. “Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” (Aísáyà 2:4) Irú àlàáfíà àti ààbò pípé bẹ́ẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ni Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa retí, kí wọ́n sì máa gbàdúrà fún nínú àdúrà tí a ń pè ní Baba Wa, tàbí Àdúrà Olúwa, wí pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:9, 10.
Ìwọ yóò ha gbádùn gbígbé nínú ayé tí ó kún fún òdodo bí ti ọ̀run? Èyí ni ìrètí tí Bíbélì gbé ka iwájú olúkúlùkù tí ó bá ń fi tọkàntọkàn wá ọ̀nà àtimọ Ọlọ́run, kí ó sì máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀nà òdodo rẹ̀.