Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Inú Àṣìṣe Àtẹ̀yìnwá
ÒFIN Ẹlẹ́dàá wa lórí ìwà híhù wà títí ayérayé, kì í sì í yí padà. Nítorí ìdí yìí, ìlànà tí a rí nínú Gálátíà 6:7 kàn wá lónìí: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” Lóòótọ́, ẹnì kan lè sọ pé òun kò ní jíhìn fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìlànà àtọ̀runwá kò ṣeé yí padà. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, kò sí ẹnì kan tí kò ní jíhìn fún àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.
Ẹnì kan tí ó gbé ìgbésí ayé oníwà wíwọ́, tí ó yí padà, tí ó sì di ìránṣẹ́ Ọlọ́run ńkọ́? Ó ṣì lè ní láti kojú àwọn àbájáde ìgbésí ayé rẹ̀ àtijọ́. Àmọ́ ṣá o, èyí kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run kò tí ì dárí jì í. Panṣágà tí Dáfídì Ọba ṣe pẹ̀lú Bátí-ṣébà mú ìjàǹbá wá sínú ìgbésí ayé rẹ̀. Kò lè yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ó ronú pìwà dà, ó sì rí ìdáríjì Ọlọ́run gbà.—2 Sámúẹ́lì 12:13-19; 13:1-31.
Ọkàn rẹ ha ń bà jẹ́ nígbà tí o bá jìyà àbájáde àṣìṣe tí o ti ṣe sẹ́yìn bí? Bí o bá fojú tí ó tọ́ wò ó, kíkábàámọ̀ lè rán wa létí láti ‘ṣọ́ra kí a má ṣe yíjú sí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́.’ (Jóòbù 36:21) Bẹ́ẹ̀ ni, kíkábàámọ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ṣíṣe àṣìṣe kan náà léraléra. Èyí tí ó tún dára jù ni pé, Dáfídì kò lo ìrírí tí ó ní nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀ láti ṣe ara rẹ̀ nìkan láǹfààní ṣùgbọ́n ó lò ó láti ṣe àwọn ẹlòmíràn láǹfààní pẹ̀lú. Ó wí pé: “Èmi yóò kọ́ àwọn olùrélànàkọjá ní àwọn ọ̀nà rẹ, kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá lè yí padà tààràtà sọ́dọ̀ rẹ.”—Sáàmù 51:13.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Dáfídì kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá pẹ̀lú Bátí-ṣébà