Ṣé Ọ̀rọ̀ Rẹ Ń Gúnni Lára Ni Àbí Ó Ń Múni Lára Dá?
NÍ ÀWỌN àkókò tí ó nira wọ̀nyí, kò yani lẹ́nu rárá pé ọ̀pọ̀ jẹ́ “oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà,” àwọn mìíràn sì jẹ́ ẹni tí “a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀.” (Sáàmù 34:18) Nípa báyìí, nínú ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó hàn gbangba pé ó ṣe pàtàkì láti máa “sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́,” kí a sì “máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera” nígbà gbogbo. (1 Tẹsalóníkà 5:14) Ṣùgbọ́n bí èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa bá ṣẹ̀ wá tàbí tí ó ṣe ohun tó burú jáì ńkọ́? Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, a lè rò pé ó tọ́ kí a láálí onítọ̀hún. Àmọ́ ṣá o, ó yẹ kí a ṣọ́ra. Ìmọ̀ràn, àní nígbà tí ó bá tọ́ pàápàá, lè ṣèpalára bí a bá fúnni lọ́nà lílekoko. Òwe 12:18 sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.”
Nítorí náà, nígbà tí a bá fẹ́ tọ́ni sọ́nà tàbí tí a bá fẹ́ yanjú èdèkòyédè, ó ṣe pàtàkì láti rántí apá kejì Òwe 12:18 pé: “Ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” Máa béèrè lọ́wọ́ ara rẹ nígbà gbogbo pé, ‘Bí mo bá nílò ìtọ́sọ́nà, báwo ni n óò ṣe fẹ́ kí a bá mi lò?’ Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa máa ń tètè dáhùn padà sí ìṣírí ju ṣíṣe lámèyítọ́ wa lọ. Nítorí náà máa gbóríyìn fúnni ní fàlàlà. Lọ́pọ̀ ìgbà, èyí yóò fún oníláìfí náà láǹfààní láti ṣàtúnṣe, ó sì ṣeé ṣe kí ó túbọ̀ kún fún ìmoore fún ìrànwọ́ tí o pèsè.
Ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa tutù! Ọ̀rọ̀ ìmúniláradá yóò mú kí ẹni tí a ń bá sọ̀rọ̀ nímọ̀lára gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ti wí, ẹni tí ó kọ̀wé pé: “Bí olódodo bá gbá mi, yóò jẹ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́; bí ó bá sì fi ìbáwí tọ́ mi sọ́nà, yóò jẹ́ òróró ní orí, èyí tí orí mi kì yóò fẹ́ láti kọ̀.”—Sáàmù 141:5.