ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 8/1 ojú ìwé 31
  • Ǹjẹ́ Ikú Tí Ń Pa Aráyé Ló Pa Màríà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ikú Tí Ń Pa Aráyé Ló Pa Màríà?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 8/1 ojú ìwé 31

Ǹjẹ́ Ikú Tí Ń Pa Aráyé Ló Pa Màríà?

GẸ́GẸ́ bí ìwé ìròyìn Vatican L’Osservatore Romano ti sọ, ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì nípa Ìgbàsókè-Ọ̀run ni pé: “Wúńdíá Aláìlẹ́ṣẹ̀, tí kò ní àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́dá, ni a gba ara àti ọkàn rẹ̀ sókè sínú ògo ti ọ̀run, nígbà tí ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé parí.” Ìwé ìròyìn ọ̀ún sọ pé ẹ̀kọ́ yìí ti mú kí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì kan sọ pé Màríà “kò kú, pé kíámọ́sá ní a sì ti gbé e dìde láti ìwàláàyè ti orí ilẹ̀ ayé sínú ògo ti ọ̀run.”a

Láìpẹ́ yìí, Póòpù John Paul Kejì ṣàlàyé tí ó yàtọ̀ lórí ọ̀ràn náà. Nínú Àpérò Gbogbogbòò ti Vatican tí ó wáyé ní June 25, 1997, ó wí pé: “Májẹ̀mú Tuntun kò pèsè ìsọfúnni kankan lórí bí Màríà ṣe kú. Ìsọfúnni tí kò sí yìí lè mú kí a dórí èrò náà pé ikú tí ń pa aráyé ló pa á, kò sì sí kúlẹ̀kúlẹ̀ kankan nípa rẹ̀ tí ó nílò àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. . . . Èrò tí ó fẹ́ yọ ọ́ kúrò lára àwọn tí ikú tí ń pa aráyé pa kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá.”

Ọ̀rọ̀ tí Póòpù John Paul sọ nípa ẹ̀kọ́ Ìlóyún Mímọ́ yìí tú àṣìṣe ńláǹlà fó. Bí ó bá jẹ́ òótọ́ ni ìyá Jésù “kò ní àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́dá” báwo ni “ikú tí ń pa aráyé,” èyí tí ó jẹ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù tàtaré rẹ̀, ṣe wá pa Màríà? (Róòmù 5:12) Ẹ̀kọ́ tí ó wá di ẹtì sí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì lọ́rùn yìí jẹ́ nítorí èrò òdì tí ó ní nípa ìyá Jésù. Abájọ nígbà náà tí ìyapa àti ìdàrúdàpọ̀ fi dìde nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì lórí ọ̀ràn yìí.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì fi Màríà hàn gẹ́gẹ́ bí onírẹ̀lẹ̀, olùṣòtítọ́, àti olùfọkànsìn, kò fi àwọn ànímọ́ yìí fún “ìlóyún mímọ́” kan. (Lúùkù 1:38; Ìṣe 1:13, 14) Bíbélì wulẹ̀ sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Bẹ́ẹ̀ ni, Màríà jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé gẹ́gẹ́ bí ìyókù aráyé ti jogún rẹ̀, kò sì sí ẹ̀rí kankan pé ikú tó pa á yàtọ̀ sí èyí tí ń pa aráyé.—Fi wé 1 Jòhánù 1:8-10.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ìgbàsókè-Ọ̀run—Ìgbàgbọ́ Aláìjampata Tí Ọlọ́run Ṣípayá Ha Ni Bí?” nínú Ilé-Ìṣọ́nà February 15, 1994, ojú ìwé 26 sí 29.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́