Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Fífi Ìrẹ̀lẹ̀ Tẹ̀ Lé Ọ̀nà Jèhófà
“Ẹ WÁ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé.” Ìkésíni yìí, tí wòlíì Hébérù nì, Sefanáyà, polongo ní ohun tí ó lé ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún sẹ́yìn, ni a ṣì nawọ́ rẹ̀ sí àwọn ènìyàn jákèjádò ilẹ̀ ayé lónìí. (Sefanáyà 2:3) Kí ni ó túmọ̀ sí láti wá Jèhófà? Ṣíṣe èyí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbígba ìmọ̀ Ọlọ́run alààyè tòótọ́ kan ṣoṣo náà, Jèhófà, sínú.—Jeremáyà 10:10; Jòhánù 17:3.
Ṣùgbọ́n, gbígba ìmọ̀ sínú kò fúnra rẹ̀ túmọ̀ sí níní ìdúró rere níwájú Ọlọ́run. Láti lè jèrè ojú rere Ọlọ́run, ẹnì kan gbọ́dọ̀ lo ìmọ̀ yìí. Lọ́nà wo? Nípa fífi ìrẹ̀lẹ̀ mú kí ìrònú àti ìṣe rẹ̀ bá ìlànà Ọlọ́run mu, gẹ́gẹ́ bí ìrírí tó tẹ̀ lé e yìí láti Suriname ti fi hàn.—Éfésù 4:22-24.
Eddy, olùkọ́ kan tí ó ti lé ní ọmọ 30 ọdún, ń yán hànhàn fún ìdáhùn tí ó tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè bí: ‘Ipa wo ni ìsìn ń kó láwùjọ òde òní?’ àti pé, ‘Ǹjẹ́ Bíbélì, ìwé ìgbàanì kan, bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní mu?’ Nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn sí i, tí wọ́n sì pèsè àwọn ìdáhùn tí ó wá láti inú Bíbélì sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, Eddy tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́. Ó tilẹ̀ tún kọ nǹkan sílẹ̀ láti lè ṣàyẹ̀wò bóyá àlàyé Àwọn Ẹlẹ́rìí rí bẹ́ẹ̀.
Tẹ́lẹ̀ rí, ìsìn kan tí ó kọ́ ọ pé ènìyàn jẹ́ àbárèbábọ̀ àtúntò iṣẹ́ Ọlọ́run lórí àwọn ìnàkí ni Eddy ń dara pọ̀ mọ́. Nítorí náà nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí fún un ní ìtẹ̀jáde náà, Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? kíá ló gbà á. Àlàyé ṣíṣe kedere tí ìwé náà ṣe nípa àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìṣẹ̀dá wú u lórí. Nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó dá a lójú pé òun ti rí òtítọ́!
Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ó wá dojú kọ ìdánwò kan. Eddy ń gbé nínú ilé kan tí ìwà olè jíjà àti àbòsí ti jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé wọn. Nípa báyìí, yíyan kan wà níwájú rẹ̀: yálà láti tẹ̀ lé ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn tí wọ́n jọ ń gbélé tàbí kí ó kọ irú ìwà bẹ́ẹ̀, kí ó sì máa gbé ìgbésí ayé tí ó fògo fún Ọlọ́run. Lọ́nà tí ó bá ọgbọ́n mu, Eddy yan èyí tí ó kẹ́yìn. Ó já gbogbo ẹgbẹ́ búburú, ó sì kó jáde nílé náà.—1 Kọ́ríńtì 15:33, 34.
Eddy tẹ̀ síwájú gidigidi lẹ́yìn tí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ìwọṣọ àti ìmúra rẹ̀ tún gbé pẹ́ẹ́lí sí i, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó kọ́. Lẹ́yìn náà, ayọ̀ rẹ̀ pọ̀ sí i nígbà tí a tẹ́wọ́ gbà á láti máa nípìn-ín nínú ìwàásù “ìhìn rere” ní gbangba. (Mátíù 24:14; Ìṣe 20:20) Ní December ọdún 1996, ọjọ́ tí ó ti ń wọ̀nà fún tipẹ́tipẹ́ náà dé nígbà tí ó fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jèhófà hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi.
Lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbàárùn-ún àwọn aláìlábòsí ọkàn ń dáhùn padà sí ìkésíni náà láti “wá Jèhófà.” Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n rí òtítọ́ ohun tí Òwe 22:4 sọ pé: “Ìyọrísí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.” Bẹ́ẹ̀ ni, nípa fífi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé ọ̀nà Jèhófà, àwọn tí ó fẹ́ òtítọ́ ń gbádùn irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí, wọ́n sì ń fi ìgbọ́kànlé fojú sọ́nà fún ìbùkún ayérayé níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé.—Sáàmù 37:29.
[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 18]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Òkun Caribbean
GUYANA
SURINAME
FRENCH GUIANA
BRAZIL
[Credit Line]
Àgbáyé: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.