Iṣẹ́ Tí “Kò Lè Ṣàìjèrè Ọ̀wọ̀”
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pétérù gba àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nímọ̀ràn pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo.” (1 Pétérù 2:12) Tipẹ́tipẹ́ ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ítálì ti ń fi irú ìwà àtàtà bẹ́ẹ̀ hàn. Ní fífi ìtọ́ni tí Jésù fún wọn láti “wàásù . . . láti orí ilé” sílò, wọ́n ṣe gbogbo iṣẹ́ tí ó yẹ kí wọ́n ṣe gẹ́gẹ́ bí Kristẹni ní gbangba, lójú gbogbo ènìyàn. (Mátíù 10:27; Jòhánù 18:20) Lójú ìwòye èyí, nígbà tí agbẹjọ́rò ará Ítálì kan àti àlùfáà kan tẹ àwọn ẹ̀sùn kan jáde pé, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ “ẹ̀ya ìsìn tí ó gbórúkọ rù lásán,” tí ó sì kà wọ́n mọ́ “àwọn ẹgbẹ́ awo tí ń fòògùn mú ènìyàn,” Àwọn Ẹlẹ́rìí pinnu láti pẹjọ́ nítorí ọ̀rọ̀ ìdójútini wọ̀nyẹn.
Nínú ẹjọ́ àkọ́kọ́, ilé ẹjọ́ dájọ́ pé agbẹjọ́rò àti àlùfáà náà kò rú òfin kankan. Àmọ́, ní July 17, 1997, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti Venice fagi lé ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ náà ṣe, ó sì dá àwọn olùjẹ́jọ́ méjèèjì náà lẹ́bi. Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn náà sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè ba ìfùsì ‘Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà’ jẹ́ ló kún inú àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì tí wọ́n tẹ̀ jáde náà. Ó jọ pé ẹ̀rí wà pé nítorí àtipẹ̀gàn àwọn ẹlẹ́sìn náà lójú ayé ni wọ́n ṣe kọ àwọn àpilẹ̀kọ náà.” Ilé ẹjọ́ náà sọ pé, àwọn àpilẹ̀kọ náà “kì í ṣe ojúlówó ọ̀nà tí a ń gbà lo ẹ̀tọ́ ìròyìn àti ìṣelámèyítọ́.” Ilé ẹjọ́ náà bu owó ìtanràn fún àwọn abanijẹ́ méjèèjì náà, ó sì tún pàṣẹ fún wọn láti san gbogbo owó tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ná sórí ẹjọ́ méjèèjì fún wọn.
Ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti Venice ṣe, tí a kọ sílẹ̀ kà pé: “Kìkì nípa mímú kí gbogbo mùtúmùwà jàǹfààní gbogbo ẹ̀tọ́ tí Òfin [ilẹ̀ Ítálì] mú dáni lójú, kí a sì rí i pé ó fìdí múlẹ̀ ni a fi lè dènà onírúurú àìráragba-nǹkan àti ìgbawèrèmẹ́sìn.” Ìdájọ́ náà gbà pé iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ọ̀ràn bòókẹ́lẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ìsìn tí ó gbórúkọ rù lásán. Ilé ẹjọ́ náà sọ pé: “Láti ka Àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́ àwọn ẹgbẹ́ awo kò tilẹ̀ fọ̀wọ̀ hàn fún ọ̀pá ìdiwọ̀n òtítọ́ ìtàn rárá, níwọ̀n bí ìsìn yìí ti wà ní ọ̀pọ̀ ìlú ńlá, tí iṣẹ́ ìyílọ́kànpadà tí àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ ń ṣe, pàápàá ní ọjọọjọ́ Sunday àti àwọn ọjọ́ ìsinmi mìíràn, sì jẹ́ èyí tí a mọ̀ dunjú, tí kò lè ṣaìjèrè ọ̀wọ̀ nítorí àwọn ìsapá tí wọ́n ń ṣe, láìka ohun yòówù kí ẹnì kan lè máa rò nípa ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń wàásù rẹ̀ sí.” Nítorí èyí, àkọsílẹ̀ ìwàásù àfìtaraṣe àti ìwà àwòfiṣàpẹẹrẹ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ítálì ti ṣèrànwọ́ láti mú ẹ̀tanú tí àwọn ènìyàn ní sí wọn kúrò.—Mátíù 5:14-16; 1 Pétérù 2:15.