“Ẹ Di Ohun Tí Ẹ Ní Mú Ṣinṣin”
Àwùjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí kan ń wàásù ní ọ̀kan nínú nǹkan bí 30 erékùṣù tó para pọ̀ dí Àwọn Erékùṣù Cyclades ní Gíríìsì. Bí méjì nínú wọn ṣe ń lọ lójú pópó, wọ́n pàdé ọlọ́pàá kan tó ní kí wọ́n bá òun dé àgọ́ ọlọ́pàá. Kò pẹ́ tí wọ́n dé àgọ́ ọlọ́pàá náà, agogo tẹlifóònù dún. Àlùfáà abúlé náà ni. Ó ní: “Mo gbọ́ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà láàárín abúlé.” Ọlọ́pàá náà dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, mo ní méjì lọ́dọ̀.” Àlùfáà ní: “Mo ń bọ̀ báyìíbáyìí.” Bí ìjíròrò náà ṣe lọ mú kí àwọn arákùnrin náà ṣojo lọ́nà kan ṣáá.
Ṣùgbọ́n, nígbà tí àlùfáà náà dé, ó rẹ́rìn-ín músẹ́, ó bọ̀ wọ́n lọ́wọ́, ó sì jókòó lórí àga tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọlọ́pàá náà. Bí ìjíròrò náà ṣe ń tẹ̀ síwájú, ọlọ́pàá náà bẹ̀rẹ̀ sí ṣe akatakítí, ṣùgbọ́n àlùfáà náà ń fọgbọ́n ṣe, ó sì ń hùwà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ó sọ fún ọlọ́pàá náà pé kí ó má fojú tín-ínrín Àwọn Ẹlẹ́rìí, ó sì fi kún un pé: “Kò sí ìbéèrè tí wọn kò lè dáhùn nítorí pé wọ́n ń gbà ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run. Yóò rọrùn láti yí ìpìlẹ̀ ayé padà ju kí a yí ìgbàgbọ́ ọ̀kan nínú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà padà lọ.”
Nígbà tí àwọn arákùnrin náà ń wàásù lọ́jọ́ kejì, wọ́n tún bá àlùfáà náà pàdé, wọ́n sì bi í pé: “Èé ṣe tí o fi hùwà sí wa bí ọ̀rẹ́ lákòókò ìjíròrò tí a ṣe ní àgọ́ ọlọ́pàá?” Àlùfáà náà sọ fún wọn pé, òun ti mọ ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ní Syros, òun sì ti ń ka Ilé Ìṣọ́ àti Jí! láti ọ̀pọ̀ ọdún wá. Ní gidi, lọ́pọ̀ ìgbà ló ti mú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ pa mọ́ sínú àpamọ́wọ́ kan, tí ó sì ń lò ó láti fi wàásù ní ṣọ́ọ̀ṣì. Ó wí pé: “N kò rò pé ìgbésí ayé ì bá nítumọ̀ bí n kò bá ní àwọn ìwé yín lọ́wọ́. Òun ló ń fún mi nírètí.”
Lẹ́yìn náà, àlùfáà náà sọ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí náà pé: “Mo ní ohun kan láti sọ fún yín. Ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin. Ẹ má ṣe àṣìṣe láti kúrò nínú ìsìn yín. Ohun tí mo ń sọ fún yín yìí ni ìwàásù tí ó dára jù tí mo tíì ṣe rí, ọ̀rọ̀ ẹnu lásán sì kọ́; bó ṣe wà lọ́kàn mi gan-an ni mo sọ ọ́ jáde.”