Ǹjẹ́ Gbogbo Àlùfáà Gba Ohun Tí Wọ́n Ń kọ́ni Gbọ́?
ỌKỌ obìnrin náà ṣẹ̀ṣẹ̀ kú ni. Àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ sọ pé ìwà ọkọ rẹ̀ kò dára tó láti lọ sí ọ̀run tààrà, ìwà rẹ̀ kò sì burú tó láti wọ ọ̀run àpáàdì. Nítorí náà, àlùfáà náà sọ pé, ó ń jìyà lọ́wọ́, títí yóò fi dára tó ẹni tí ń wọ ọ̀run. Ó sanwó fún àlùfáà náà pé kí ó bá òun gbàdúrà, kí ó máà pẹ́ tí a ó fi dá ọkọ òun sílẹ̀ kúrò níbi ìjìyà ìwẹ̀mọ́ náà. Èyí tẹ́ opó náà lọ́rùn, ó sì rò pé àlùfáà náà ní irú ìgbàgbọ́ àtọkànwá tí òun ní.
Ǹjẹ́ o rò pé kò ní jẹ́ ìjákulẹ̀ fún obìnrin náà, bí ó bá wá mọ̀ pé àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì òun kò gbà gbọ́ pé a ń fìyà jẹni lẹ́yìn ikú? Ìdààmú ń bá ọ̀pọ̀ ènìyàn nígbà tí wọ́n bá wá mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àlùfáà ni kò gba ọ̀pọ̀ lára ohun tí àwọn fúnra wọn ń kọ́ni gbọ́. Nígbà tí ìwé ìròyìn National Catholic Reporter, ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó pè ní “ìṣòro tó ju ọ̀ràn ìbálòpọ̀ lọ láàárín àwọn àlùfáà,” ó wí pé: “Láàárín àwọn àlùfáà lápapọ̀, ọ̀pọ̀ ni kò gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà mọ́, wọn kò gba ẹ̀kọ́ ìsìn nípa ẹ̀san àti ìjìyà tàbí àjíǹde gbọ́ mọ́ . . . àwọn àlùfáà sì ti sọ irú àìgbàgbọ́ yìí di apá kan ìrònú wọn.”
Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì mìíràn ní irú ìṣòro kan náà. Ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn Canberra Times ti Ọsirélíà sọ pé, ìwádìí kan láàárín àwọn adelé àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ England fi hàn pé ọ̀pọ̀ “kò gba àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ Kristẹni àtayébáyé, bí wúńdíá kan tó bímọ, àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù, àti wíwá lẹ́ẹ̀kejì ti Mèsáyà, gbọ́ mọ́.”
Òǹkọ̀wé nípa ìsìn, George R. Plagenz, béèrè bí ẹ̀rí ọkàn kò ṣe ń yọ àlùfáà kan lẹ́nu nígbà tí ó bá ń ka ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ kan tí òun alára kò gbà gbọ́. Àlùfáà kan sọ pé òun wulẹ̀ máa ń yí ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ náà, “Mo gbà . . . gbọ́,” padà ni. Ó wí pé: “Mo máa ń bẹ̀rẹ̀ ní sísọ pé, ‘WỌ́N gba Ọlọ́run Baba Olódùmarè gbọ́ . . . ’” Plagenz pe irú àgàbàgebè bẹ́ẹ̀ ní “jìbìtì tó tóbi jù ní orílẹ̀-èdè náà.”
Ó bani nínú jẹ́ pé irú àìnígbàgbọ́ àti àìṣòótọ́ bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn àlùfáà ti fa ìjákulẹ̀ nípa ìsìn lápapọ̀ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ṣùgbọ́n òun nìkan kọ́ ni ohun tí ń dani láàmú nípa ìsìn lónìí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ẹni tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n ti kọ́ pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ kò ní yà wọ́n lẹ́nu láti mọ̀ pé Bíbélì kò fi ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tí wọ́n ti tẹ́wọ́ gbà tipẹ́tipẹ́ nínú ṣọ́ọ̀ṣì kọ́ni? Àpilẹ̀kọ tí ó kàn yìí yóò ṣàyẹ̀wò àpẹẹrẹ kan.