ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 12/1 ojú ìwé 32
  • Ìfẹ́ Tó Ju Ti Ìyá Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìfẹ́ Tó Ju Ti Ìyá Lọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 12/1 ojú ìwé 32

Ìfẹ́ Tó Ju Ti Ìyá Lọ

ÀWỌN ìyá ìkókó máa ń gbé ọmọ wọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí jù sí àwọn ibùdókọ̀ abẹ́lẹ̀, ilé ìgbọ̀nsẹ̀ ti gbogbo gbòò, tàbí kí wọ́n gbé wọn jù sílẹ̀ ní àwọn òpópónà tí èrò ń wọ́ tìrítìrí. Nígbà mìíràn, àwọn akópàǹtírí tilẹ̀ ti bá àwọn ọmọ ọwọ́ pínníṣín nínú agolo pàǹtírí, tí wọ́n ti ké ké ké tó ti sú wọn nítorí àìrí ìyá wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn O Estado de S. Paulo ti sọ, “ọ̀ràn àwọn ọmọ tí a ń gbé jù sílẹ̀ ní òpópónà túbọ̀ ń pọ̀ sí i.” Àmọ́ ṣá o, ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ ìyá ìkókó náà lè kábàámọ̀ ìpinnu rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Síbẹ̀, ó gbé ọmọ náà jù nù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè yọrí sí ikú fún ọmọ náà.

O lè ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo ni ìyá kan ṣe lè ronú kan gbígbé ọmọ rẹ̀ jù nù láìbìkítà nípa ọjọ́ ọ̀la?’ Bíbélì lo irú ipò ìbànújẹ́ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àfiwé láti fúnni ní irú ìmọ̀lára tí ó yàtọ̀ tí Ẹlẹ́dàá wa ní sí àwọn tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀: “Aya ha lè gbàgbé ọmọ ẹnu ọmú rẹ̀ tí kì yóò fi ṣe ojú àánú sí ọmọ ikùn rẹ̀? Àní àwọn obìnrin wọ̀nyí lè gbàgbé, síbẹ̀, èmi kì yóò gbàgbé.”—Aísáyà 49:15.

Lóòótọ́, Ọlọ́run ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ sí wa, ó sì ń bìkítà gidigidi nípa àìní wa, ju bí ìyá èyíkéyìí tí ó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn ti lè ṣe lọ. Ọmọdé ni ọ́ tàbí àgbàlagbà, ìṣòro èyíkéyìí tí ó lè dojú kọ ọ́, o kò dá nìkan wà. Ẹlẹ́dàá rẹ fẹ́ ràn ọ́ lọ́wọ́, ó sì fẹ́ kí ó dára fún ọ. Onísáàmù sọ pé, “bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.”—Sáàmù 27:10.

Jákèjádò ayé, a ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! jáde láti fúnni ní ìmọ̀ “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo,” Jèhófà, àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, èyí tí ó lè túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn tí wọ́n bá fi ìmọrírì gbà á sínú.—Jòhánù 17:3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́