A Mú Orúkọ Ọlọ́run Padà Bọ̀ Sípò
“LẸ́YÌN tí wọ́n ti yọ orúkọ Jèhófà kúrò nínú àwọn Bíbélì fún ọ̀pọ̀ ọdún, àní ó tilẹ̀ lè jẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún pàápàá, àwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀ òde òní nìkan ni ẹ̀sìn Kristẹni tó ń jà fún tetragrammaton,a tó sì mú un padà bọ̀ sípò.”
Àwọn ọ̀rọ̀ òkè yìí wá láti inú ìwé náà, Jeová dentro do Judaísmo e do Cristianismo (Jèhófà nínú ẹ̀sìn àwọn Júù àti ti Kristẹni), láti ọwọ́ òǹkọ̀wé ará Brazil náà, Assis Brasil. Ṣùgbọ́n a lè béèrè pé, Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì mélòó kan ni a ti lo orúkọ Ọlọ́run lọ́nà kan tàbí òmíràn, èé ṣe táwọn ẹ̀sìn yòókù fi yọ ọ́ kúrò nínú Bíbélì wọn? Brasil sọ pé: “Wọ́n mú orúkọ Ọlọ́run kúrò, bóyá tìtorí ìgbàgbọ́ òdì . . . , tàbí torí ìdí tó jẹ́ pé àwọn nìkan ló yé, tàbí torí ìfẹ́ láti gbé orúkọ Jésù àti ti Màríà, ìyá rẹ̀ ga.”
Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gbẹ́ni Brasil ti tọ́ka sí i lọ́nà tó tọ́: “Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Potogí ti ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àtúnṣe sí yíyọ tí wọ́n yọ orúkọ [Ọlọ́run] sọnù.” Lọ́nà wo? Ní ti pé a ti mú orúkọ Jèhófà padà bọ̀ sípò tó yẹ ẹ́ nínú Bíbélì yẹn. Orúkọ Jèhófà fara hàn ní iye ìgbà tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé igba [7,200] nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
Láti ìgbà táa kọ́kọ́ gbé Bíbélì òde òní yìí, táa tú láìlábùlà, jáde lédè Potogí, ẹ̀dà tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà àtààbọ̀ la ti pín kiri. Nípa báyìí, akọ̀ròyìn kan tó ń kọ̀ròyìn fún ìwé ìròyìn Brazil náà, Diário do Nordeste (Ìwé Ìròyìn Ojoojúmọ́ Apá Ìlà Oòrùn Àríwá) ni a sún láti béèrè pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Ọlọ́run ní orúkọ?” Ọpẹ́lọpẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì òde òní yìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn lè dáhùn nísinsìnyí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni. Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lédè Hébérù, báa ṣe ń kọ orúkọ Ọlọ́run nìyí יהוה. Lẹ́tà mẹ́rin yìí (tí a máa ń kà láti ọwọ́ ọ̀tún sí òsì) la sábà máa ń pè ní Tetragrammaton [lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tí ó dúró fún orúkọ Ọlọ́run].